Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

MAY 15, 2017
HAITI

Iṣẹ́ Ìrànwọ́ Ń Parí Lọ Lẹ́yìn Tí Ìjì Hurricane Matthew Jà ní Haiti

Iṣẹ́ Ìrànwọ́ Ń Parí Lọ Lẹ́yìn Tí Ìjì Hurricane Matthew Jà ní Haiti

Ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù tún òrùlé ilé yìí ṣe.

ÌLÚ PORT-AU-PRINCE, lórílẹ̀-èdè Haiti—Ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Hurricane Matthew ni ìjì tí wọ́n sọ pé ó lágbára jù tó tíì jà lórílẹ̀-èdè Haiti láti ohun tó lé ní àádọ́ta [50] ọdún sẹ́yìn. October 4, 2016 ló jà lórílẹ̀-èdè náà, ìjì runlé rùnnà ni, ohun tó sì bà jẹ́ pọ̀ gan-an ju ti ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé lọ́dún 2010. Bó ṣe jáde ní abala Ìròyìn lórí ìkànnì jw.org ní October 24, 2016, gbàrà tí àjálù náà ṣẹlẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́kọ́ dìde ìrànwọ́, tí wọ́n kó oúnjẹ, oògùn àti àgọ́ ránṣẹ́ sáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Àwọn Ẹlẹ́rìí fara balẹ̀ wo bí àjálù náà ṣe rinlẹ̀ tó, nígbà tó wá di January 1, 2017, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò ìrànwọ́ láwọn ọ̀nà míì, ní ti pé wọ́n yan ìgbìmọ̀ mẹ́ta pé kí wọ́n máa bójú tó àwùjọ mẹ́rìnlá [14] tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé, àwọn àwùjọ náà sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í tún àwọn ilé tí iye wọn jẹ́ igba ó lé mẹ́ta [203] tó bà jẹ́ ṣe. June 2017 ni wọ́n ṣètò pé iṣẹ́ ìrànwọ́ tí wọ́n ń ṣe yìí máa parí.

Daniel Lainé, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn nílùú Port-au-Prince, sọ pé: “Ìdí tá a fi ń ṣe iṣẹ́ yìí ni ká lè pèsè ilé tó bójú mu fún gbogbo àwọn ará wa tí ìjì náà ba ilé wọn jẹ́ gan-an.” Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ò rọrùn. Ọ̀gbẹ́ni Lainé ṣàlàyé pé ìjì náà ba ọ̀nà jẹ́, kò sì jẹ́ kí fóònù ṣiṣẹ́ láti máa fi pe àwọn èèyàn. Ó sọ pé, “Ó mú kí iṣẹ́ ìrànwọ́ tá à ń ṣe yìí nira.” Nígbà tó fi máa di April 20, iṣẹ́ ti parí lórí ilé mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [96], iṣẹ́ sì ń lọ lọ́wọ́ lórí àwọn ilé míì tí iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n [30].

Smith Mathurin, igbákejì aṣojú Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin fún àgbègbè Paillant àti Petite Rivière de Nippes.

Àwọn aláṣẹ ìlú gbà pé iṣẹ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Smith Mathurin, tó jẹ́ igbákejì aṣojú Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin fún àgbègbè Paillant àti Petite Rivière de Nippes, tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ gan-an, sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù gangan ni iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe, wọ́n tún ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́.” Ó fi kún un pé: “Mo mọrírì ìrànlọ́wọ́ ńlá táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lẹ́yìn tí ìjì Hurricane Matthew jà. Àwọn èèyàn nílò ìrànwọ́ lásìkò yẹn, ẹ sì dìde ìrànwọ́, ẹ ò kàn jókòó sínú ṣọ́ọ̀ṣì yín, kẹ́ ẹ máa wò wọ́n níran.”

Ẹnì kan ń fi òrùlé tuntun kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe han aṣojú tó wá láti oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Láti oríléeṣẹ́ wa nílùú Warwick ní New York ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí, wọ́n ń lo ọrẹ táwọn èèyàn fi ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń ṣe kárí ayé.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Haiti: Daniel Lainé, +509-2813-1560