Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JUNE 26, 2017
GUATEMALA

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Lágbára Wáyé Nítòsí Ààlà Tó Wà Láàárín Guatemala àti Mẹ́síkò

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Lágbára Wáyé Nítòsí Ààlà Tó Wà Láàárín Guatemala àti Mẹ́síkò

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí lórílẹ̀-èdè Guatemala. Ní Wednesday, June 14, 2017, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára wáyé ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà, nítòsí ààlà orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ìròyìn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ látọ̀dọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ni pé ìmìtìtì ilẹ̀ náà pa, ó kéré tán, èèyàn márùn-ún, ó sì mú kí ilẹ̀ ya káàkiri.

Ìkankan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé láwọn ibi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ ò fara pa, wọn ò sì ṣèṣe. Àmọ́ ibi mọ́kànlá [11] tí wọ́n ti ń jọ́sìn àti mẹ́tàdínlógún [17] lára àwọn ilé wọn ló bà jẹ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Central America, tó wà nílùú Mẹ́síkò, ti ṣètò ìgbìmọ̀ mẹ́ta tó ń ṣètò ìrànwọ́ ní Guatemala kí wọ́n lè mọ ibi tí nǹkan bà jẹ́ dé, kí wọ́n sì rí sí bí nǹkan pàjáwìrì táwọn èèyàn nílò ṣe máa tètè dé ọ̀dọ̀ wọn.

Láti oríléeṣẹ́ wa ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí, wọ́n ń lo owó táwọn èèyàn fi ń ti iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Mẹ́síkò: Gamaliel Camarillo, +52-555-133-3048

Guatemala: Juan Carlos Rodas, +502-5967-6015