Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

OCTOBER 20, 2015
GHANA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣèrànwọ́ Ní Gbàrà tí Omíyalé Ṣẹlẹ̀ Lórílẹ̀-èdè Ghana

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣèrànwọ́ Ní Gbàrà tí Omíyalé Ṣẹlẹ̀ Lórílẹ̀-èdè Ghana

ACCRA, Ghana—Nígbà tó fi máa di ìparí oṣù August 2015, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti parí ètò ìrànwọ́ nígbà àjálù tá à ń ṣe ní Accra tí í ṣe olú-ìlú Ghana. Omíyalé ba ìlú yìí jẹ́ ó sì tún fi ẹ̀mí àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì (200) ṣòfò.

Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ń nàka sí ibi tí omi dé lára ilé ará wọn kan tí omi bà jẹ́.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò kú, síbẹ̀ nǹkan bí igba ó lé àádọ́ta (250) Ẹlẹ́rìí lomi yìí ba ilé wọn jẹ́. Lọ́jọ́ kejì ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ìyẹn June 4, 2015, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Ghana ṣètò ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù. Iṣẹ́ wọn ni kí wọ́n pèsè ohun tí àwọn tí àjálù dé bá nílò, bí aṣọ ìbora, aṣọ tí wọ́n á wọ̀ àti oúnjẹ. Ìgbìmọ̀ yìí tún ṣètò láti tún àwọn ilé tí omi bà jẹ́ ṣe. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé lágbègbè Accra náà ṣèrànwọ́, wọ́n gba àwọn ará wọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn sílé lákòókò yẹn.

Dossou Amevor (lápá òsì nísàlẹ̀) tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù ń mójú tó bí wọ́n á ṣe pín fóòmù ní gbọ̀ngàn ìjọba Atiman tó wà ní Madina, nílùú Accra.

Omíyalé yìí mú kí ilé epo kan laná, ó sì ba àwọn páìpù omi tó wà ní Adabraka jẹ́, ni omi ò bá lè débẹ̀ mọ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wá gbé táǹkì omi ńlá kan sí Gbọ̀ngàn Ìjọba (ibi ìjọsìn) tó wà ní Adabraka kí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ àti àwọn aládùúgbò lè jọ máa lò ó.

Ní Saturday, June 6, ẹ̀ka ọ́fíìsì rán àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ dókítà márùn-ún àti nọ́ọ̀sì méjì, wọ́n wá pín wọn sí méjì kí wọ́n lè lọ bójú tó àwọn tí àjálù náà kàn nílùú Alajo àti Adabraka. Oríṣiríṣi àìsàn ni wọ́n wò, lára ẹ̀ ni ibà, àìsàn igbáàyà àti ìgbẹ́ gbuuru. Aṣojú tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán wá àtàwọn Ẹlẹ́rìí míì náà lọ ṣèbẹ̀wò sí àwọn ará wọn tí àjálù náà kàn láti fi Bíbélì tù wọ́n nínú, kí wọ́n sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.

Dókítà mẹ́ta àti nọ́ọ̀sì méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba Adabraka, inú Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí ni wọ́n ti ń tọ́jú àwọn èèyàn.

Nathaniel Gbedemah tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ghana sọ pé: “Àdánù àti ẹ̀mí àwọn èèyàn tí omíyalé yìí fi ṣòfò nílùú Accra dùn wá gan-an. Gẹ́gẹ́ bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ṣe láwọn orílẹ̀-èdè míì tírú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀, à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi Bíbélì tu àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn nínú, ká fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ká sì pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000

Ghana: Nathaniel Gbedemah, tel. +233 30 701 0110