Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

NOVEMBER 24, 2017
FINLAND

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Pa dà Sẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Níbi Térò Pọ̀ Sí Ní Turku lórílẹ̀-èdè Finland

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Pa dà Sẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Níbi Térò Pọ̀ Sí Ní Turku lórílẹ̀-èdè Finland

HELSINKI—Àwọn afẹ̀míṣòfò pa èèyàn ní ìlú Turku lórílẹ̀-èdè Finland ní August 18, 2017. Àmọ́ ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, inú àwọn òṣìṣẹ́ ìlú dùn gan-an láti rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní gbàgede ọjà yẹn.

Ọ̀gbẹ́ni Teemu Rissanen tó ń mójú tó gbàgede ọjà tó wà nílùú Turku sọ pé: “Ó ti mọ́ wa lára láti máa rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbí. Ó ya àwọn ará ìlú lẹ́nu pé wọn ò rí àwọn Ajẹ́rìí fún ọjọ́ mélòó kan, ṣe ni wọ́n ń béèrè pé ‘Ibo ni wọ́n lọ?’ Ìwà àwọn Ajẹ́rìí dáa, a sì fẹ́ràn bí wọ́n ṣe ń fi àtẹ ìwé wọn wàásù ní gbàgede ọjà níbí.”

Veikko Leinonen, tó jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Finland, sọ pé: “A mọrírì báwọn aláṣẹ ìlú ṣe mára tù wá àti báwọn aráàlú Turku ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ wa jẹ wọ́n lọ́kàn. Kódà àwọn aláṣẹ ti fún wa láyè láti máa lo ṣọ́ọ̀bù kékeré kan fúngbà díẹ̀ tó ṣe é forí pamọ́ sí, tó sì máa pèsè ààbò níwọ̀nba. A láyọ̀ láti máa sọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fáwọn aládùúgbò wa ní ìlú Turku.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Finland: Veikko Leinonen, +358-400-453-020