Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

APRIL 29, 2016
ECUADOR

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Ecuador

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Ecuador

Ní April 16, 2016, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára kan wáyé ní Etí Òkun Pàsífíìkì lórílẹ̀-èdè Ecuador. Ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn àti ilẹ̀ tó sẹ̀ léraléra lẹ́yìn náà ṣọṣẹ́ gan-an, àwọn tó sì lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti àádọ́ta (650) ni ẹ̀mí wọn lọ sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò pa ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Ecuador lára, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé etíìgbọ́ wa tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kú. Àwọn Ẹlẹ́rìí ti fi àwọn ọkọ̀ akẹ́rù kó oúnjẹ àti omi tó ṣeé mu ránṣẹ́ síbi tí ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé. Ojú ẹsẹ̀ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ti rán ìgbìmọ̀ méjì tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù síbẹ̀ kí wọ́n kọ́kọ́ lọ máa bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ, lẹ́yìn náà, wọ́n ṣètò ibi méjì tí wọ́n á ti máa pèsè ìrànwọ́, ọ̀kan ní ìlú Pedernales, èkejì ní ìlú Manta. Bákan náà, aṣojú mẹ́rin láti ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lọ síbi tí ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbé àwọn èèyàn ró.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000

Ecuador: Marco Brito, tel. +593 98 488 8580