Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JULY 25, 2017
DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE CONGO

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣèrànwọ́ Fáwọn tí Ìjà Tó Wáyé Lórílẹ̀-èdè Kóńgò Pa Lára

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣèrànwọ́ Fáwọn tí Ìjà Tó Wáyé Lórílẹ̀-èdè Kóńgò Pa Lára

Belinda (a ò ní sọ orúkọ ọkọ rẹ̀ torí àwọn ìdí kan) àti mẹ́ta nínú àwọn ọmọ rẹ̀ rèé ní ilé ìwòsàn kan nílùú Dundo, ní Àǹgólà. Kóńgò ni wọ́n ti pa ọkọ ẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ kan sì wà tí wọ́n ṣì ń wá di báyìí. Ìbọn ba Belinda àti Ritinha, ọmọbìnrin rẹ̀ tó kéré jù, ọmọ ọlọ́dún méjì, ó sì gba pé kí wọ́n gé ẹsẹ̀ ọmọ náà. Ọmọbìnrin rẹ̀ míì tún fara pa níbi táwọn kan ti ń fi àdá jà.

ÌLÚ KINSHASA, ní Kóńgò—Wàhálà ti ń ṣẹlẹ̀ lágbègbè Kasai ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kóńgò, àwọn èèyàn sì ń para wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kó nǹkan ránṣẹ́ sáwọn ará wọn tó fara gbá wàhálà yìí, wọ́n sì ń fi Bíbélì tù wọ́n nínú. Bí àwọn ẹ̀yà ṣe dédé ń bára wọn jà ní Kóńgò yìí, táwọn ológun tú sígboro, tí ìlú ò sì fara rọ ti mú kí àwọn èèyàn tó ju mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [1,300,000] sá kúrò nílùú, tó fi mọ́ àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] tó ti sá kúrò ní Kasai lọ sí orílẹ̀-èdè Àǹgólà tó wà nítòsí wọn. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó ń sá lọ yìí ni àwọn jàǹdùkú ti ká mọ́ ojú ọ̀nà, tí wọ́n sì ṣèṣe gan-an. Ó wá gba pé kí wọ́n gbàtọ́jú nílé ìwòsàn nígbà tí wọ́n dé Àǹgólà. Iná ti jó àwọn míì lára, àwọn míì sì ti fara gbọgbẹ́ gan-an torí àwọn jàǹdùkú ṣá àwọn kan ládàá, wọ́n sì yin àwọn míì níbọn. Ìròyìn tá a gbọ́ báyìí ni pé àwọn tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé àádọ́rin [870] lára àwọn tó sá wá sí Àǹgólà ló jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tàwọn ti àwọn ọmọ wọn kéékèèké. Ó kéré tán, mẹ́wàá nínú wọn ló fara pa. Ó sì dùn wá pé, Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìlélógún [22] la gbọ́ pé wọ́n ti pa báyìí.

Aṣojú kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Àǹgólà wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn alàgbà kan tó wá láti Àǹgólà àti Kóńgò, wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ló sì lé àwọn kan lára wọn kúrò nílùú.

Robert Elongo, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn nílùú Kinshasa sọ pé, “Ó dùn wá pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló fara gbá ọ̀rọ̀ ìjà tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, pàápàá bó ṣe jẹ́ pé ọmọ kéékèèké làwọn kan nínú wọn. Torí pé àwọn kan wà nítòsí ibì kan ti wàhálà ti ṣàdédé ṣẹlẹ̀ ni wọ́n ṣe fara pa, bẹ́ẹ̀, jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ wọn ni wọ́n wà. Ọ̀rọ̀ àwọn ará wa ń jẹ wá lọ́kàn gan-an, a ò fẹ́ kí nǹkan kan ṣe wọ́n, a sì ti sọ fún wọn kí wọ́n máa rọra ṣe. Àwa tá a wà níbí àtàwọn ará wa tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Àǹgólà ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè pèsè ohun táwọn ará wa nílò fún wọn, ká lè dúró tì wọ́n, ní pàtàkì, ká sì lè fi Bíbélì tù wọ́n nínú.”

Àwọn èèyàn yìí sá kúrò nílùú ní Kóńgò torí àwọn tó ń jà, wọ́n sá lọ sínú igbó, wọ́n wá ń kọ́ abà kan síbẹ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Àǹgólà àti Kóńgò ti ṣètò àwọn ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ kí wọ́n máa bójú tó ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó nílò ìrànwọ́ yìí. Lára àwọn ohun táwọn èèyàn fi ṣètọrẹ tí wọ́n ti kó lọ sọ́dọ̀ àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí ni aṣọ bẹ́ẹ̀dì, aṣọ tó ṣeé wọ̀, oúnjẹ, nẹ́ẹ̀tì tí kì í jẹ́ kí ẹ̀fọn jẹni àti bàtà. Àpapọ̀ àwọn nǹkan yìí wúwo ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31,000] kìlógíráàmù lọ. Bákan náà, wọ́n ti kó àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ilé ìwòsàn tí wọ́n á máa fi tọ́jú àwọn èèyàn yìí ránṣẹ́, àpapọ̀ wọn wúwo tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti márùndínlọ́gbọ̀n [525] kìlógíráàmù. Dókítà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ti lọ síbi tí àwọn tó sá wá láti Kóńgò wà kó lè tọ́jú àwọn márùndínlógóje [135] tí wọ́n nílò ìtọ́jú pàjáwìrì.

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Àǹgólà àti Kóńgò ti lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí ogun abẹ́lé yìí lé wá, kí wọ́n lè fi Bíbélì tù wọ́n nínú. Wọ́n tiẹ̀ tún bá wọn ṣe àwọn ìpàdé kan lákànṣe, kí wọ́n lè sọ àwọn àsọyé tó dá lórí Bíbélì tó bá ohun tójú wọn ti rí mu. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èdè Potogí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ lórílẹ̀-èdè Àǹgólà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò láti máa ṣèjọsìn lédè Tshiluba, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn èdè mẹ́rin tí wọ́n ń sọ jù ní Kóńgò, káwọn èèyàn tí ogun lé wá lè jàǹfààní. Fọ́tò wọn ló wà lókè pátápátá yìí.

Láti oríléeṣẹ́ wa nílùú Warwick, ní New York ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí, wọ́n ń lo owó táwọn èèyàn fi ń ti iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Àǹgólà: Todd Peckham, +244-923-166-760

Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kóńgò: Robert Elongo, +243-81-555-1000