Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

APRIL 24, 2017
COLOMBIA

Ẹrẹ̀ Ya ní Gúúsù Orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà, Ó sì Pa Ọ̀pọ̀ Èèyàn

Ẹrẹ̀ Ya ní Gúúsù Orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà, Ó sì Pa Ọ̀pọ̀ Èèyàn

Ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ Saturday, April 1, 2017, odò mẹ́ta kún ya nítòsí ìlú Mocoa, olú ìlú Putumayo, àgbègbè kan ní orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà. Èyí mú kí ẹrẹ̀ ya wọ̀lú, ó sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn. Ó ṣeni láàánú pé ìròyìn tá a gbọ́ látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà ni pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ, Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì sì wà tí wọ́n ṣì ń wá. Yàtọ̀ síyẹn, ìdílé márùn-ún tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ò nílé lórí mọ́. Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèrànwọ́ lẹ́yìn àjálù yìí. Wọ́n ti ń pèsè oúnjẹ, omi tó ṣeé mu, epo pẹtiróòlù àti ilé táwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí máa gbé. Àwọn tó jẹ́ alàgbà nínú wọn tún ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbé àwọn èèyàn ró. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn ṣì ń bójú tó gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n sì ń kọ́wọ́ ti báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Kòlóńbíà: Wilson Torres, +57-1-8911530