Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

FEBRUARY 2, 2017
CHILE

Iná Jẹ Ọ̀pọ̀ Igbó Run ní Chile

Iná Jẹ Ọ̀pọ̀ Igbó Run ní Chile

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará wọn àtàwọn míì tó wà níbi tí iná ńlá ti jó igbó lọ rẹpẹtẹ. Iná ti jẹ ilẹ̀ tó lé ní mílíọ̀nù kan éékà run ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Chile àti apá gúúsù orílẹ̀-èdè náà. Ó ti tó ọ̀sẹ̀ méjì ti iná yìí ti ń jó lọ́pọ̀ àgbègbè, àwọn aláṣẹ sì ń sọ pé irú ẹ̀ ò tíì ṣẹlẹ̀ rí lórílẹ̀-èdè náà.

Ìròyìn tá a gbọ́ látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Chile ni pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò fara pa, iná yìí ò sì pa ìkankan nínú wọn. Ó di dandan káwọn kan kó kúrò níbi tí wọ́n wà, àmọ́ àwọn ará wọn gbà wọ́n sílé.

Yàtọ̀ síyẹn, ilé márùn-ún tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni iná jó run. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí ti wá ṣètò ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù kí wọ́n lè máa rí sí i pé ètò wà láti ran àwọn tí àjálù dé bá lọ́wọ́.

Láti oríléeṣẹ́ wa ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò bá a ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá, wọ́n ń lo owó táwọn èèyàn fi ń ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Chile: Jason Reed, +56-2-2428-2600