Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

NOVEMBER 4, 2016
CAMEROON

Ọkọ̀ Ojú Irin Ṣubú ní Kamẹrúùnù, Ó sì Pa Àwọn Èèyàn

Ọkọ̀ Ojú Irin Ṣubú ní Kamẹrúùnù, Ó sì Pa Àwọn Èèyàn

Láàárọ̀ ọjọ́ Friday, October 21, 2016, ọkọ̀ ojú irin kan tó ń gbé àwọn èèyàn lọ sílùú Douala, tó wà létíkun kan lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù, ṣubú lójú ọ̀nà ní tòsí ìlú Eseka. Nǹkan bí ọgọ́fà [120] kìlómítà sílùú Yaoundé, tó jẹ́ olú-ìlú Kamẹrúùnù ni jàǹbá yìí ti ṣẹlẹ̀. Àwọn tó ṣèṣe níbẹ̀ lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600], àwọn tó sì lé ní àádọ́rin [70] ló kú.

Mẹ́rìndínlógún [16] ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣèṣe. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sì kú nínú jàǹbá náà, ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin [65] ni, alàgbà sì ni nínú ìjọ kan nílùú Douala. Ó bà wá nínú jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí mú ẹ̀mí ọ̀kan nínú àwọn ará wa lọ, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tí àjálù yìí dé bá àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn dùn wá gan-an.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Kamẹrúùnù: Gilles Mba, 237-6996-30727