Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

FEBRUARY 25, 2016
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Pe Gbogbo Èèyàn Kárí Ayé sí Ìrántí Ikú Kristi Tá A Máa Ń Ṣe Lọ́dọọdún

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Pe Gbogbo Èèyàn Kárí Ayé sí Ìrántí Ikú Kristi Tá A Máa Ń Ṣe Lọ́dọọdún

A máa sọ àsọyé kan tó dá lórí Bíbélì níbi Ìrántí Ikú Kristi náà.

NEW YORK—Ní Saturday, February 27, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa bẹ̀rẹ̀ sí í pé gbogbo èèyàn sí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tá a kà sí pàtàkì jù lọ nínú ọdún, ìyẹn ni Ìrántí Ikú Kristi, tó máa wáyé ní March 23. David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílé-iṣẹ́ wa ní New York, sọ pé: “Ìrántí Ikú Kristi yìí máa ní àsọyé kan tó ṣàlàyé bí ikú tí Jésù kú ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn ṣe ṣàǹfààní fún wa lóde òní, tó sì fún wa nírètí nípa ọjọ́ ọ̀la. Gbogbo èèyàn la pè síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí, kí wọ́n lè wá jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a máa gbádùn níbẹ̀.”

Ní gbogbo àsìkò náà, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ló máa dìídì lọ sí ilé àwọn aládùúgbò wa láti pè wọ́n wá sí ìpàdé pàtàkì yìí. Lọ́dún tó kọjá, nǹkan bí ogún mílíọ̀nù èèyàn ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000