Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

APRIL 30, 2015
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sọ Nípa Àpéjọ Wọn Tọdún 2015 Tó Máa Bẹ̀rẹ̀ Síí Wáyé Láti Oṣù May

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sọ Nípa Àpéjọ Wọn Tọdún 2015 Tó Máa Bẹ̀rẹ̀ Síí Wáyé Láti Oṣù May

NÍ NEW YORK—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ àpéjọ àgbègbè wọn ti ọdún 2015 lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní oṣù May 22. Àpéjọ àgbègbè ọdún 2015 “Máa Tẹ̀ lé Àpẹẹrẹ Kristi!” la máa ṣe kárí ayé títí wọ oṣù January ọdún 2016. Lọ́sẹ̀ mẹ́tà kí àpéjọ náà tó bẹ̀rẹ̀, àwọn ará máa késí àwọn èèyàn kí wọ́n lè wá síbi àpéjọ náà lọ́fẹ̀ẹ́.

Arákùnrin J. R. Brown tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílé-iṣé tó wà ní Brooklyn, New York sọ pé “Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ ti ọdún yìí jẹ́ ká rí Jésù Kristi bíi ẹni àmọ̀káyé, àti pé àpẹẹrẹ rere tọ́ yẹ kí gbogbo èèyàn lọ́mọdé lágbà máa tẹ̀lé ni, láìka ẹ̀yà tàbí àṣà wa sí. A gbà pé gbogbo àwọn tó bá wà máa gbádùn ìjíròrò nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì láyé Jésù. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọdún yìí máa jẹ́ lọ́nà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, á sì tún máa wo fídíò alárinrin tó gbádùn mọ́ni, táá sì kọ́ wa ní bá a ṣe lé jàǹfààní nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́.”

Àwọn ọjọ́ àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe àpéjọ àgbègbè ọdún 2015 “Máa Tẹ̀ lé Àpẹẹrẹ Kristi!” wà lórí ìkànnì wa ìyẹn, jw.org/yo. Fún àlàyé síwájú si, àwọn akọ̀ròyìn lè lọ sí ẹ̀ka-iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè wọn, tàbí tí wọ́n bá fẹ́ mọ orúkọ iléeṣẹ́ agbéròyìnjáde tó máa rán àwọn oníròyìn lọ sí ibi àpéjọ náà.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000