Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

MARCH 20, 2015
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

À Ń Retí Ogún Mílíọ̀nù Èèyàn Níbi Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

À Ń Retí Ogún Mílíọ̀nù Èèyàn Níbi Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

NÍ NEW YORK—Lẹ́yìn tóòrùn bá wọ̀ lọ́jọ́ Friday, April 3, 2015, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe Ìrántí ikú Kristi, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí la kà sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ́dún. Níbẹ̀, a máa gbọ́ àsọyé oníṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta [45] tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ǹjẹ́ O Mọyì Ohun Tí Kristi Ṣe Fún Ọ!” Láwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ kó tó di ọjọ́ pàtàkì yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa pín ìwé ìkésíni kárí ayé láti pe àwọn aládùúgbò wa, ọ̀rẹ́, àtàwọn èèyàn wa síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí.

J. R. Brown, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílé-iṣẹ́ wa ní Brooklyn, lórílẹ̀-èdè New York, sọ pé: “Lọ́dún tó kọjá, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jáde láti pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí ikú Kristi, tó já sí pé nǹkan bíi ogún mílíọ̀nù èèyàn lápapọ̀ ló pésẹ̀ síbẹ̀. Lọ́dún yìí, à ń retí pé àwọn tó máa wá ju iye yẹn lọ.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000