Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

MAY 16, 2017
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Bẹ̀rẹ̀ Àpéjọ Àgbègbè Tọdún Yìí

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Bẹ̀rẹ̀ Àpéjọ Àgbègbè Tọdún Yìí

ÌPÍNLẸ̀ NEW YORK—Ní May 19, 2017, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa bẹ̀rẹ̀ àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. Àkòrí tọdún yìí ni “Má Sọ̀rètí Nù!” A máa ṣe àpéjọ yìí láwọn ibì kan tá a ti ṣètò kárí ayé, a sì máa ṣe é wọ ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2018. Bá a ṣe ṣe láwọn ọdún tó ti kọjá, a ti bẹ̀rẹ̀ sí í kàn sí gbogbo èèyàn kárí ayé, ká lè pè wọ́n wá sí àpéjọ yìí.

Ọ̀fẹ́ làyè ìjókòó níbi àwọn àpéjọ yìí, a kì í sì í gbégbá ọrẹ. David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wa nílùú Warwick, ní New York sọ pé: “Lọ́dún tó kọjá, àwọn tó wá sí àpéjọ àgbègbè tá a ṣe kárí ayé fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́tàlá [13]. À ń retí pé a máa pọ̀ jùyẹn lọ lọ́dún yìí.”

Apá méjìléláàádọ́ta [52] ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà pín sí, oríṣiríṣi ọ̀nà la sì máa gbà ṣe é, àwọn kan máa jẹ́ àsọyé ṣókí, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, a sì tún máa wo àwọn fídíò kéékèèké. Bákan náà, ní ọ̀sán ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, a máa wo apá kọ̀ọ̀kan nínú fíìmù alápá mẹ́ta kan tá a pe àkòrí rẹ̀ ní Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì. Ọjọ́ tá a máa ṣe àpéjọ kọ̀ọ̀kan àtàwọn ibi tá a ti máa ṣe é wà lórí ìkànnì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn jw.org/yo. Àwọn oníròyìn lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sún mọ́ wọn jù tí wọ́n bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, bí àpẹẹrẹ, orúkọ aṣojú wa tí wọ́n lè kàn sí tí wọ́n bá fẹ́ gbé ìròyìn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àpéjọ kan sáfẹ́fẹ́.

Ọ̀gbẹ́ni Semonian sọ pé: “Àwọn ìṣòro tá à ń kójú láyé máa ń tánni lókun, kì í jẹ́ kọ́kàn ẹni balẹ̀, ó tiẹ̀ máa ń mú káwọn kan sọ̀rètí nù. Kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni àpéjọ wa tọdún yìí máa ṣe láǹfààní, ó tún máa ṣe àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí láǹfààní torí pé ó máa ran gbogbo wa lọ́wọ́ ká lè máa fàyà rán ìṣòro, ká sì máa fara dà á tayọ̀tayọ̀.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000