Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

MAY 4, 2016
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ìdúróṣinṣin ni Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ọdún 2016 Dá Lé

Ìdúróṣinṣin ni Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ọdún 2016 Dá Lé

NEW YORK—Gbogbo èèyàn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè sí Àpéjọ Àgbègbè ti ọdún 2016, àkòrí rẹ̀ ni “Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà!” Friday, May 20, ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà máa bẹ̀rẹ̀ àpéjọ yìí. Kárí ayé la máa ṣe é, ọ̀fẹ́ sì ni.

Ọjọ́ mẹ́ta la máa fi ṣe àpéjọ yìí, a máa gbádùn àsọyé mọ́kàndínláàádọ́ta [49], ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì máa dá lé ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ náà, ìyẹn “ìdúróṣinṣin.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ti dìídì ṣe fídíò kéékèèké márùnlélọ́gbọ̀n [35] tí wọ́n máa gbádùn níbẹ̀ àti fíìmù méjì tí wọ́n máa wò lọ́jọ́ Saturday àti Sunday. Ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, àwọn fídíò orin tí wọ́n dìídì ṣètò fún àpéjọ yìí ni wọ́n máa fi bẹ̀rẹ̀ apá ti àárọ̀ àti tọ̀sán.

Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe lọ́dọọdún, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa fi àkànṣe ìwé ìkésíni pe gbogbo èèyàn wá sí àpéjọ yìí. Àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe àpéjọ kọ̀ọ̀kan wà lórí ìkànnì wọn, jw.org. Àwọn akọ̀ròyìn lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sún mọ́ wọn jù lọ tí wọ́n bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àpéjọ yìí. Bákan náà, àwọn oníròyìn tó bá fẹ́ gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà sáfẹ́fẹ́ lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó sún mọ́ wọn jù lọ láti mọ orúkọ agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣojú fún àgbègbè náà.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn tó wà ní ìlú Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York sọ pé: “Ó dá wa lójú pé kí àwọn ẹni méjì tó lè bá ara wọn ṣọ̀rẹ́ kalẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ dúró ti ara wọn gbágbáágbá. Àpéjọ wa ti ọdún yìí máa jẹ́ káwọn èèyàn lè ṣe ara wọn lọ́kan; láàárín ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ni pàtàkì jù lọ wọ́n á túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Ó dá wa lójú pé gbogbo àwọn tó bá wá sí àpéjọ yìí máa gbádùn ẹ̀ gan-an.”

Agbẹnusọ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000