Apá Kẹta nìyí nínú àpilẹ̀kọ alápá mẹ́ta tó dá lórí ohun táwọn gbajúmọ̀ ọ̀mọ̀wé nípa ẹ̀sìn, ohun tó ń lọ láwùjọ àti òṣèlú tá a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ àti ohun táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n míì sọ, ìyẹn àwọn tó mọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé ìjọba Soviet àti lẹ́yìn tí wọ́n kógbá wọlé.

ÌLÚ ST. PETERSBURG, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà—Ilé ẹjọ́ ti sọ pé kí iléeṣẹ́ Center for Sociocultural Expert Studies nílùú Moscow ṣàyẹ̀wò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ìwé ẹ̀sìn wọn dáadáa. Wọ́n parí àyẹ̀wò kan ní August 2015, òun ni wọ́n sì fi ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ẹjọ́ lórí Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, àmọ́ àyẹ̀wò míì ṣì ń lọ lọ́wọ́.

Dr. Mark R. Elliott

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n táwọn èèyàn kà sí pàtàkì láwùjọ, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn orílẹ̀-èdè míì ti já irọ́ àwọn àyẹ̀wò yìí. Ọ̀kan lára wọn ni Dr. Mark R. Elliott, tó ń gbé abala ìròyìn East-West Church and Ministry Report jáde. Ó sọ pé: “Àwọn tí ìjọba kà sí ‘ọ̀jọ̀gbọ́n’, tí wọ́n ní kí wọ́n máa ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, títí kan àwọn tó ń ta ko Bíbélì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ni kò ní ìmọ̀, tí wọn ò sì ṣeé fọkàn tán, torí pé àwọn ohun tí wọ́n ń sọ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀.”

Dr. Roman Lunkin

Dr. Roman Lunkin, tó jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka Center for Religion and Society Studies ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Institute of Europe, Russian Academy of Sciences nílùú Moscow, dìídì jẹ́ kí iléeṣẹ́ Center for Sociocultural Expert Studies mọ̀ pé “ìkankan nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yẹn ò kẹ́kọ̀ọ́ yege nípa ẹ̀sìn, wọn ò tiẹ̀ tún mọ ohun tó máa ń wà nínú ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Iléeṣẹ́ Irenaeus of Lyon Centre ni wọ́n ti gba àwọn ìsọfúnni kan tí wọ́n fi ṣe àyẹ̀wò tí wọ́n ń ṣe. Àwọn ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tí wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ló sì ni iléeṣẹ́ yìí, wọ́n máa ń gbógun ti àwọn ẹgbẹ́ ìsìn, àwọn èèyàn sì mọ̀ wọ́n mọ bí wọ́n ṣe ń ta ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀sìn míì.”

Dr. Ekaterina Elbakyan

Dr. Ekaterina Elbakyan, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá àti ohun tó ń lọ láwùjọ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Moscow Academy of Labor and Social Relations sọ pé, “Kó má yà yín lẹ́nu pé mo gbà pẹ̀lú Dr. Lunkin. Òótọ́ ni pé lóde òní, ní Rọ́ṣíà, àwọn tí kì í ṣe akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni wọ́n máa ń sọ pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n á sì ti fi ohun tí wọ́n á sọ sí wọn lẹ́nu. Ẹni tó bá jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n gangan ò wá ní ráyè sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.”

Dr. Elbakyan wà nílé ẹjọ́ ìlú Taganrog lẹ́ẹ̀mejì nígbà tí wọ́n ń dá ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì tún wà níbi ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nílùú Rostov-on-Don gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ̀n. Ó sọ pé: “Mo fojú ara mi rí fídíò tó mú kí wọ́n fẹ̀sùn agbawèrèmẹ́sìn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Pẹ̀lú ìmọ̀ tí mo ní gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n, ẹ̀ẹ̀mejì ni mo ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ ní ilé ẹjọ́ pé báwọn Kristẹni ṣe máa ń ṣe ìsìn wọn ló wà nínú fídíò tá a wò yẹn, pé kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn agbawèrèmẹ́sìn, àmọ́ ilé ẹjọ́ ò ka ọ̀rọ̀ mi sí. Ó hàn kedere pé ọgbọ́kọ́gbọ́n tí àwọn aláṣẹ fẹ́ máa fi ṣe ẹ̀tanú ẹ̀sìn nìyí. Tí wọ́n bá sì ń bá a lọ báyìí, kò sí tàbí ṣùgbọ́n, wọ́n á ka àwọn ẹlẹ́sìn sí ‘agbawèrèmẹ́sìn’ torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, 7-812-702-2691