Apá Kejì nìyí nínú àpilẹ̀kọ alápá mẹ́ta tó dá lórí ohun táwọn gbajúmọ̀ ọ̀mọ̀wé nípa ẹ̀sìn, ohun tó ń lọ láwùjọ àti òṣèlú tá a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ àti ohun táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n míì sọ, ìyẹn àwọn tó mọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé ìjọba Soviet àti lẹ́yìn tí wọ́n kógbá wọlé.

ÌLÚ ST. PETERSBURG, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà—Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Róṣíà fẹ́ fòfin de Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, wọ́n ní ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni.

Dr. Ekaterina Elbakyan

Ibi tọ́rọ̀ náà burú sí ni pé, tí ilé ẹjọ́ bá dá wọn lẹ́bi lórí ọ̀rọ̀ yìí, tí wọ́n sì fòfin de Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, Dr. Ekaterina Elbakyan tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá àti ohun tó ń lọ láwùjọ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Moscow Academy of Labor and Social Relations sọ pé ó máa “ta ko àtunṣe tí wọ́n ṣe sí Àpilẹ̀kọ Kẹta nínú Òfin orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tó dá lórí Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn, èyí tí Ọ̀gbẹ́ni Putin fọwọ́ sí nígbà ìwọ́wé ọdún 2015.” Ohun tí Àpilẹ̀kọ Kẹta òfin náà tí wọ́n tún ṣe sọ ni pé: “Bíbélì, Quran, ìwé Tanakh àti Kangyur, àwọn ohun tó wà níbẹ̀ àtàwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá fà yọ látinú rẹ̀ ò ṣeé kà sí ti agbawèrèmẹ́sìn.”

Dr. Roman Lunkin

Dr. Roman Lunkin, tó jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka Center for Religion and Society Sociocultural Expert Studies ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Institute of Europe, Russian Academy of Sciences nílùú Moscow sọ pé: “Ta ló lè rò ó pé òfin tí ìjọba ṣe kí mìmì kankan má bàa mi àwọn ìwé mímọ́ kan máa sún wọn fẹ́ fòfin de àwọn ìwé mímọ́ míì? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Bíbélì tí wọ́n ń lò ló kọ́kọ́ forí fá a báyìí.”

Dr. Jeffrey Haynes

Dr. Jeffrey Haynes, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa òṣèlú àti ọ̀gá iléeṣẹ́ Centre for the Study of Religion, Conflict and Cooperation London Metropolitan University fi kún un pé, “Rọ́ṣíà wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn ICCPR [ìyẹn, International Covenant on Civil and Political Rights], torí náà, tí wọ́n bá lọ fòfin de Bíbélì yẹn, ṣe ni wọ́n ń ta ko òmìnira ẹ̀sìn tí wọ́n fọwọ́ sí, táwọn orílẹ̀-èdè míì náà sì fọwọ́ sí.”

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg, tó wà ní kìlómítà méjìdínlógóje [138] sí àríwá ìwọ̀ oòrùn ìlú St. Petersburg, ni wọ́n ti ń ṣe ẹjọ́ tó dá lórí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ní April 26, 2016, lọ́jọ́ kejì tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ náà, adájọ́ gba ohun tí àwọn alátako àwọn Ẹlẹ́rìí sọ pé kí ilé ẹjọ́ ṣì dá ẹjọ́ náà dúró, kí wọ́n sì yan àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó máa ṣàyẹ̀wò Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ilé ẹjọ́ ò fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láǹfààní kí wọ́n gbèjà ara wọn, wọ́n sì yan iléeṣẹ́ Center for Sociocultural Expert Studies pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò lórí ọ̀rọ̀ náà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀rọ̀ tí kò dáa tí iléeṣẹ́ yìí ti sọ nípa Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ni wọ́n fi kọ́kọ́ fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí ilé ẹjọ́ tún ṣe wá yàn wọ́n kí wọ́n gbé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun yẹ̀ wò ta ko òfin tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Róṣíà ṣe pé, tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan bá ti kọ́kọ́ sọ èrò rẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan tó wà nílé ẹjọ́, kò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ yẹn mọ́.

Dr. Gerhard Besier

Ọ̀rọ̀ ṣì wà lórí àyẹ̀wò tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n lọ ṣe, àmọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé ti sọ èrò wọn lórí Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde yìí. Ọ̀kan lára wọn ni Dr. Gerhard Besier, tó jẹ́ ọ̀gá iléeṣẹ́ Sigmund Neumann Institute for the Research on Freedom and Democracy. Ó sọ pé: “Kárí ayé làwọn ọ̀mọ̀wé nípa Bíbélì tí wọ́n wá láti onírúurú ẹ̀sìn ti ń gbóríyìn fáwọn tó túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

Bákan náà, nínú ìròyìn oṣooṣù tí àjọ SOVA Center for Information and Analysis tó wà ní Moscow gbé jáde ní February 2016, èyí tí wọ́n pè ní Misuse of Anti-Extremism, àjọ náà sọ pé: “A ò rí ẹ̀rí kankan pé ìwé agbawèrèmẹ́sìn ni Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.” Látìgbà yẹn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé oṣooṣù ni àjọ SOVA Center ń sọ ọ́ nínú ìròyìn tí wọ́n ń gbé jáde pé àwọn ò fara mọ́ ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń ṣe. Wọ́n sọ ọ́ nínú ìròyìn tí wọ́n gbé jáde ní June 2016: “À ń tún un sọ báyìí pé ẹ̀tanú ẹ̀sìn la ka inúnibíni táwọn èèyàn ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà sí, ẹ̀tanú ẹ̀sìn ni àwọn aláṣẹ sì ń ṣe sí wọn bí wọ́n ṣe ń fòfin de ẹ̀sìn wọn àti àwọn ìwé wọn.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, 7-812-702-2691