NEW YORK—Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti ń gbọ́ ẹjọ́ yìí láti ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn, ilé ẹjọ́ náà kéde lónìí pé àwọn fọwọ́ sí ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ, pé kí ìjọba ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà pa, títí kan ibi márùn-dín-nírínwó [395] tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin káàkiri orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ojú ẹsẹ̀ ni ìjọba máa bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀.

Yaroslav Sivulskiy, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí bà wá nínú jẹ́, ó sì kó ìrònú bá wa, torí à ń wo ipa tí èyí máa ní lórí ìjọsìn wa. A máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ọ̀rọ̀ yìí, a sì retí pé láìpẹ́, ìjọba á jẹ́ ká pa dà máa ṣe àwọn ohun tá a lẹ́tọ̀ọ́ sí lábẹ́ òfin, torí pé ẹlẹ́sìn àlàáfíà ni wá.”

Oṣù kan ni wọ́n fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà pé kí wọ́n fi pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta ló sì máa gbọ́ ẹjọ́ náà.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, +7-911-087-8009