NEW YORK—Ní Saturday tó kọjá yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣí oríléeṣẹ́ wọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sílùú Warwick ní New York sílẹ̀ kí àwọn èèyàn lè wá wo ibẹ̀. Wọ́n ṣì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i lẹ́yìn eléyìí. Troy Snyder, tó jẹ́ alábòójútó ilé náà, sọ pé: “Láàárín ọ̀sẹ̀, ìpíndọ́gba ẹgbẹ̀rún kan ó lé àádọ́jọ [1,150] èèyàn ló máa ń wá rìn yí ká ọgbà oríléeṣẹ́ wa lójoojúmọ́. Àmọ́ a fẹ́ ṣí ọgbà wa sílẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ méjèèjì yìí káwọn aládùúgbò wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì tó ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá à ń kọ́ ilé yìí lè wá wo ibẹ̀. Àá lè fìyẹn dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún gbogbo ohun tí wọ́n ṣe.”

Lọ́jọ́ Saturday yẹn, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó dín márùn-ún [395] làwọn tó wá síbẹ̀. Nínú àwọn tó wá, igba ó lé márùn-ún [205] làwọn tó ń gbé ládùúgbò yẹn, àwọn oníṣòwò àtàwọn oníṣẹ́ ilé sì jẹ́ igba ó dín mẹ́wàá [190]. Àwọn Ẹlẹ́rìí pèsè jíjẹ mímú fáwọn àlejò yìí, wọ́n sì fi ogójì [40] ìṣẹ́jú mú wọn yí ká ọgbà náà. Wọ́n fi fídíò kékeré kan han àwọn àlejò náà, ìbéèrè àti ìdáhùn wá tẹ̀ lé e.

Christopher Gow, tó ń gbé ní Tuxedo Park ní New York, tó sì wà lára Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Igi Igbó nílùú náà.

Christopher Gow, tó ń gbé ní ọgbà Tuxedo Park tí kò jìnnà síbẹ̀ sọ pé: “Inú mi dùn nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kí n wá wo ọgbà wọn, ó sì ń ṣe mí bíi kí n ti wà níbẹ̀. Mo mọ ìgbà tí wọ́n ń kọ́lé yẹn, kò tiẹ̀ dà bíi pé wọ́n ń kọ́lé kankan ládùúgbò yẹn torí pé kò la ariwo lọ rárá, wọ́n ṣe é lọ́nà tó dáa.”

Torí pé etí adágún omi Blue Lake tó wà ní ọgbà Sterling Forest State Park làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ oríléeṣẹ́ wọn tuntun sí, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ládùúgbò yẹn dìídì sọ pé ó wu àwọn láti wá wo bí wọ́n ṣe ṣe é láìpa ohun tó wà ní àyíká lára.

Dr. Richard Hull, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìtàn ní New York University, tó ti fẹ̀yìn tì, tó sì jẹ́ òpìtàn ìlú Warwick ní New York lábẹ́ òfin.

Dr. Richard Hull, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìtàn ní New York University, tó ti fẹ̀yìn tì, tó wá ń gbé nílùú Warwick, tó sì jẹ́ òpìtàn ìlú náà lábẹ́ òfin sọ pé: “Ó lé ní àádọ́ta [50] ọdún tí mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tó wà lágbègbè yìí. Iṣẹ́ ńlá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe bí wọ́n ṣe kọ́ irú ilé tí wọ́n fẹ́, síbẹ̀ tí wọn ò pa àwọn ohun tó wà ní àyíká lára, kódà wọ́n tún ro ti àwọn ẹranko tó wà lágbègbè yìí.”

Lẹ́yìn táwọn àlejò rìn yí ká ọgbà oríléeṣẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Gow, tóun náà wà lára Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Igi Igbó ní Tuxedo Park, sọ pé: “Kò sí gbàrọgùdù nínú gbogbo ohun tó wà níbí, títí dórí bíńtín. Iṣẹ́ ńlá lẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Bẹ́ ẹ ṣe kọ́ ilé yín yìí lọ́nà tí kò ní pa àyíká lára wú wa lórí gan-an, àpẹẹrẹ rere ló sì jẹ́ fún gbogbo wa.”

Lẹ́yìn tí wọ́n mú àwọn àlejò náà yí ká, wọ́n tún gbà wọ́n láyè láti wo ìpàtẹ mẹ́ta tó wà lókè àti ìsàlẹ̀ ibi àbáwọlé ilé náà fúnra wọn. Méjì nínú àwọn ìpàtẹ náà dá lórí ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé àtàwọn ohun tí wọ́n ń ṣe lóde òní, ìpàtẹ kẹta sì dá lórí àwọn Bíbélì tó ṣọ̀wọ́n àtàwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé tó jẹ mọ́ Bíbélì.

Dr. Hull parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Bí wọ́n ṣe kọ́ ilé yìí bóde mu gan-an. Mo rí i pé wọ́n fara balẹ̀ ṣètò gbogbo nǹkan, wọ́n sì gbé ọ̀pọ̀ nǹkan yẹ̀ wò dáadáa kí wọ́n tó kọ́ ilé yìí. Mi ò tíì lọ wo ibi tí wọ́n kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí, mò ń retí àtipadà wá.”

Ọ̀gbẹ́ni Snyder sọ pé: “A wò ó pé ó yẹ ká ṣe ohun àrà ọ̀tọ̀ kan láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aráàlú fún bí wọ́n ṣe tì wá lẹ́yìn, tí wọ́n sì gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ látìgbà tá a ti kó débí. Torí ẹ̀ la ṣe ṣètò láti ṣí oríléeṣẹ́ wa sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì káwọn aládùúgbò wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè wá wò ó.” Àwọn tá a fún ní ìwé ìkésíni tàbí tí wọ́n ń gbé ládùúgbò yẹn àmọ́ tí wọn ò lè wá ní Saturday tó kọjá, a ti ṣètò pé kí wọ́n wá ní Saturday tó ń bọ̀ yìí, ìyẹn April 29, láti aago mẹ́wàá àárọ̀ sí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000