ÌLÚ NEW YORK—Láti oṣù August sí October 2015 ni iṣẹ́ ìkọ́lẹ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lóríléeṣẹ́ wa tuntun tó wà ní Warwick nílùú New York ti dójú agbami, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [3,800] àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ló máa ń wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lójoojúmọ́.

Láwọn ìgbà tí iṣẹ́ náà fi gbomi gan-an, àwọn ọkọ̀ akẹ́rù tó tó ogójì ni à ń lò láti fi kó àwọn òṣìṣẹ́ tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [3,800] wá síbi iṣẹ́ tí a sì fi ń gbé wọn pa dà sílé lójoojúmọ́.

Àwọn yàrá ìjẹun mẹ́jọ lá ṣe fáwọn òṣìṣẹ́ kí wọ́n lè máa jẹun níbẹ̀.

Látìgbà tí iṣẹ́ ìkọ́lé náà ti bẹ̀rẹ̀ ní July 2013, àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún [18,000] ló ti rìnrìn àjò wá láti ìpínlẹ̀ wọn kí wọ́n lè wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, kódà àwọn èèyàn máa wá ń ṣiṣẹ́ láti ìpínlẹ̀ Alaska àti Hawaii pàápàá. Tá a bá fojú bù ú, àwọn òṣìṣẹ́ tó pọ̀ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] sí ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ló ń dè síbi iṣẹ́ náà lópin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, àmọ́ láwọn ìgbà tí iṣẹ́ náà fi gbomi gan-an, iye yẹn pọ̀ sí i, ó lé ní ọgọ́rùn-ún méje [700]. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ló yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ fún ọ̀sẹ̀ kan sí ọ̀sẹ̀ mẹ́rin.

Richard Devine tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé yìí ṣàlàyé pé: “Bí àwọn òṣìṣẹ́ ṣe máa ń pọ̀ lójoojúmọ́ yìí lè fa ìkọlùkọgbà. Kí gbogbo nǹkan lè wà létòletò, ká sì lè pa àkókò mọ́, a pín àwọn òṣìṣẹ́ náà sí àwùjọ méjì, a ṣètò pé kí àwọn òṣìṣẹ́ tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] má ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láàárọ̀, pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ láti aago mẹ́ta ọ̀sán sí aago méjì òru.” Láti oṣù May títí di September ni ìṣètò pé kí àwọn kan máa ṣiṣẹ́ dòru yìí fi wáyé.

Bí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé oríléeṣẹ́ tuntun táwa Ẹlẹ́rìí ń kọ́ ṣe rí lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́.

Ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé náà ròyìn pé gẹ́gẹ́ báa ṣe ṣètò tẹ́lẹ̀, nínú àwọn ilé gbígbé mẹ́rin tá a fẹ́ kọ́, méjì máa parí tó bá fi máa di January 2016. Àmọ́ Ọ̀gbẹ́ni Devine wá sọ pé, “àkókò tá a máa fi parí gbogbo iṣẹ́ yìí ti dín lóṣù mẹ́rin sí ìgbà tá a ṣètò tẹ́lẹ̀, a dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wa.” Tó bá fi máa di September 1, 2016, a ti ṣètò pé a máa parí iṣẹ́ lórí ilé gbígbé tó kù, àwọn ọ́fíìsì àti ilé tí wọ́n ti ń ṣe àwọn iṣẹ́ míì.

Bí oríléeṣẹ́ wa tuntun ṣe rí rè é tá a bá wò ó látòkè.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000