NEW YORK—Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà parí oríléeṣẹ́ wọn tuntun tí wọ́n ń kọ́ ní August 2016, wọ́n gba àmì ẹ̀yẹ torí pé wọn ò ṣe ohun tó ń pa àyíká lára níbi ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sílùú Warwick, ní New York. Iléeṣẹ́ Green Building Initiative (GBI), tó máa ń yẹ ilé táwọn iléeṣẹ́ míì kọ́ wò, tó sì máa ń fún wọn lámì ẹ̀yẹ, ló fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin fún gbogbo ilé méje tí wọ́n kọ́ sí Warwick, tó yege nínú àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe. Àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin yìí ni àmì ẹ̀yẹ tó ga jù tí iléeṣẹ́ yìí lè fúnni.

Shaina Weinstein, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà níléeṣẹ́ GBI ní ẹ̀ka tó ń ṣètò àbẹ̀wò sáwọn iléeṣẹ́ sọ pé: “Nínú ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé márùndínláàádọ́rin [965] ilé tá a ti yẹ̀ wò lórílẹ̀-èdè yìí, mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] péré ló gba àmì ẹ̀yẹ tó ga jù, ìyẹn àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin. Ó yani lẹ́nu gan-an pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin fún ilé méjèèje tí wọ́n kọ́ sí Warwick yẹn. Ó fi hàn pé wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ omi, iná, wọn ò sì ba àyíká jẹ́ níbẹ̀.”

Ohun tí iléeṣẹ́ GBI máa ń wò kí ilé kan tó gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes nìyí. Gbogbo ilé méje tó wà ní oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iléeṣẹ́ yìí lọ yẹ̀ wò ló gba, ó kéré tán, àádọ́rùn-ún [90] máàkì nínú ọgọ́rùn-ún [100], tó já sí pé wọ́n á gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin.

Bí iléeṣẹ́ GBI ṣe sọ lórí ìkànnì wọn, wọ́n ní “àwọn kì í fi iṣẹ́ àwọn pawó, pé ṣe làwọn máa ń gbé ọ̀nà ìkọ́lé tó dáa lárugẹ, ìyẹn ni pé káwọn èèyàn lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ lọ́nà tó dáa, kí wọ́n sì kọ́lé lọ́nà tí kò ní wu ẹ̀mí léwu tàbí kó pa àyíká lára.” Iléeṣẹ́ GBI máa ń lọ wo àwọn ilé tuntun tí iléeṣẹ́ kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́, kí wọ́n lè rí i bóyá wọ́n ṣe dáadáa. Wọ́n tún máa ń sọ fún àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ míì tó mọ̀ nípa ẹ̀ pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò ìsọfúnni táwọn ti kó jọ nígbà táwọn lọ wo ilé náà. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ náà sì máa ń lọ fojú ara wọn wo bí wọ́n ṣe kọ́ ilè náà.

David Bean, tó ń rí sí ọ̀rọ̀ bíbójú tó àyíká ní iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “A mọrírì àwọn àmì ẹ̀yẹ yìí, ó jẹ́rìí sí i pé gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ sí ilé tá a kọ́ lọ́nà tí kò pa àyíká lára yìí ló ṣiṣẹ́ náà tọkàntọkàn. Ibi tó sì dáa náà ló bọ́ sí yìí, ìyẹn inú ọgbà Sterling Forest State Park.

Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́ nìyí, wọ́n gbin oríṣiríṣi ewéko márùn-ún sórí òrùlé ibẹ̀, àmọ́ wọ́n fi nǹkan tẹ́ òrùlé náà kí wọ́n tó gbìn ín kí omi má bàa máa rin wọnú ilé. Ewéko yìí máa ń sẹ́ omi òjò tó bá rọ̀ síbẹ̀ kó tó ṣàn dà nù, kó má bàa ṣàkóbá fún omi táwọn èèyàn ń lò.

Ara ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ni pé wọ́n fi àwọn igi kan sílẹ̀ lórí ilẹ̀ yẹn, wọ́n sì lo àwọn igi tí wọ́n gé níbẹ̀ fún iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Jeffrey Hutchinson, tó jẹ́ ọ̀gá tẹ́lẹ̀ ní ọgbà Sterling Forest sọ pé: “Inú mi dùn sí ohun tí wọ́n ṣe, ìyẹn bí wọ́n ṣe gé àwọn igi tó wà níbi tí wọ́n fẹ́ kọ́lé sí, tí wọ́n wá lọ là á sí pákó, tí wọ́n sì lò ó níbi ilé tí wọ́n ń kọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe dáadáa gan-an bí wọ́n ṣe kọ́ ilé yẹn lọ́nà tí kò ba àyíká jẹ́.” Shaina Weinstein náà sọ pé, Lérò tiwa, àpẹẹrẹ gidi ni ilé tí wọ́n kọ́ sílùú Warwick yẹn jẹ́, ó jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí gan-an láti kọ́lé lọ́nà tí kò ní pa àyíká lára.”

Richard Devine, tó jẹ́ alága Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé tó bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ní Warwick sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún ni ètò wa ti fi bójú tó àwọn ilé tá a ní sí Brooklyn kó lè máa lẹ́wà. Àmọ́ ní báyìí, ohun tá à ń wọ̀nà fún ni bá a ṣe máa bójú tó ilé dáradára tá a kọ́ sílùú Warwick yìí, tá ò ní ṣohun tó máa pa àyíká lára níbẹ̀, tá ò sì ní ba ọgbà Sterling Forest tó jẹ́ ọgbà ẹlẹ́wà jẹ́.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-845-524-3000