Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó yọ̀ǹda ara wọn ti ṣàtúnṣe tó kàmàmà sí Ilé Ìwòran Stanley, ìyẹn ilé ńlá pàtàkì kan tí wọ́n ti ń lò fún nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún láti ṣe àwọn àpéjọ àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí Bíbélì nílùú Jersey ni New Jersey.