ÌLÚ NEW YORK—Ní Tuesday, April 26, 2016, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ta àwọn ilé 124 Columbia Heights tó wà ní Brooklyn, nílùú New York. Ilé yìí fẹ̀ gan-an, àmì ilé ìṣọ́ kan sì wà lórí rẹ̀ tó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká. Apá àríwá ibì kan táwọn èèyàn máa ń ṣeré lọ ní àgbègbè Brooklyn Heights ni ilé yìí wà. December 2015 la gbé ilé yìí sílẹ̀ pé a máa tà á, àwọn èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá wa dúnàádúrà. Nígbà tó yá, a gbà láti tà á fún ẹnì kan nínú wọn tí ò bá wa rajà rí.

Bí ilé 122-124 Columbia Heights ṣe rí kí àwọn Ẹlẹ́rìí tó tún un ṣe.

Ilé alájà mẹ́rin tí wọ́n fi òkúta pupa kọ́ ló wà ní 124 Columbia Heights tẹ́lẹ̀, ibẹ̀ ni Ọ̀gbẹ́ni Henry Ward Beecher tó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, tó sì tún jẹ́ pásítọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Plymouth gbé láàárín ọdún 1856 sí 1881. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ ìtàn ilé yẹn, ó ní “inú ilé yìí ni wọ́n sọ pé Ààrẹ Lincoln ti lọ rí Ọ̀gbẹ́ni Beecher ṣáájú kí wọ́n tó tọwọ́ bọ ìwé Ìkéde Òmìnira fún Àwọn Ẹrú.” Ní May 1909, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ra ilé yìí, nígbà tó yá, wọ́n ra àwọn ilé míì tó wà ní tòsí kún un, gbogbo ẹ̀ ló wá para pọ̀ di ilé alájà mẹ́wàá tó gba àdúgbò kan lónìí.

Ọ̀gbẹ́ni Richard Devine, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ibi pàtàkì la ka àwọn ilé tó wà ní 124 Columbia Heights sí nínú ìtàn wa. Ibẹ̀ làwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ wa ti ń gbé látọdún 1909. Ibẹ̀ tún ni WBBR, ìyẹn iléeṣẹ́ rédíò wa ìgbà yẹn tá a fi ń gbé àsọyé Bíbélì àtàwọn ohun tó jọ ọ́ sáfẹ́fẹ́ wà látọdún 1929 sí 1957, àyàfi ọdún mẹ́rin kan tá ò lo ibẹ̀.”

Láàárín ọdún 1950 sí 1959, yàrá ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí ń lò ní iléeṣẹ́ rédíò wọn tí wọ́n ń pè ní WBBR rèé, ó wà ní 124 Columbia Heights.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún (100) ọdún táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà ní àdúgbò Brooklyn Heights, wọ́n ti kọ́kọ́ dá oríléeṣẹ́ wọn tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àjọ Watch Tower Bible and Tract Society tórúkọ rẹ̀ wà lábẹ́ òfin sílẹ̀ sí Allegheny (tó ti wà lára ìlú Pittsburgh báyìí), ní Pennsylvania láàárín ọdún 1880 sí 1889. Ọ̀gbẹ́ni David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn sọ pé: “Ohun tó mú ká kó lọ sí ibi tó wà létíkun bíi Brooklyn lọ́dún 1909 ni pé iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń ṣe kárí ayé ń fẹjú sí i, ó sì ń yára tẹ̀ síwájú.”

Àwọn ilé 124 Columbia Heights tá a tà yìí ni ìgbésẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé bá a ṣe ń múra láti kó lọ sí oríléeṣẹ́ wa tó wà ní Warwick, nílùú New York. Ilẹ̀ ibẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta (50) éékà, a ò sì ní pẹ́ kọ́ ọ tán. Ọ̀gbẹ́ni Semonian fi kún un pé: “Ó dáa gan-an bá a ṣe ń kó lọ sí oríléeṣẹ́ wa tuntun yìí torí bá a ṣe fẹ́ la ṣe kọ́ ọ. Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún tá a ti wà ní Brooklyn, àmọ́ Warwick la ti máa bẹ̀rẹ̀ ìgbà ọ̀tun.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000