Ní MAPUTO, lórílẹ̀-èdè Mozambique—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ ni òjò fi rọ̀ tí kò sì dá láti oṣù December títí wọ àárín oṣù January ládùúgbò Zambezia tó jẹ́ olú ìlú Mozambique, ọwọ́ òjò yìí le débi pé omíyalé ṣẹlẹ̀, ó sì gbẹ̀mí èèyàn tí ó tó ọgọ́jọ ó dín méjì [158]. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Mozambique ròyìn pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó kú tàbí tó fara pa. Àmọ́, omíyalé náà ba ibi méjì tá a ti ń jọ́sìn jẹ́, ìyẹn ibi tá à ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ilé àwọn ará wa tó sì bàjẹ́ jẹ́ ọgọ́rùn méjì àti mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (225).

Àwọn ará tó yọ̀ǹda ara wọn múra láti fi ọkọ̀ òfuurufú gbé oúnjẹ sọdá sí àdúgbò Chire, ní agbègbè Zambezia.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò ìgbìmọ̀ tó máa bójú tó àwọn ará wọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ ládùúgbò wọn. Wọ́n fi àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ṣe ibùgbé fún ìgbà díẹ̀ àti ibi tí wọ́n ti máa pín oúnjẹ. Ìlú Chire wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kìlómítà (1,500 km) sí ìlú Maputo, omíyalé ba àwọn afárá téèyàn lè gbà wọ àdúgbò yẹn jẹ́, tí kò sì jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tó ẹgbẹ̀rún kan lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (1,300) kọjá. Àjọ tó ń rí sí ètò Ìrìnnà Ọkọ̀ Òfuurufú nílùú Mozambique gbà kí wọ́n fi ọkọ̀ òfuurufú gbé àwọn ohun èlò tí wọ́n fẹ́ fi ṣèrànwọ́ sọdá sí àgbègbè yẹn, ẹrù náà sì tó tọ́ọ̀nù méjìdínlógún (17).

Àpò àgbàdo àti kóró àgbàdo tí wọ́n ń dì sọ́kọ̀ láti pín nílùú Morrumbala.

Arákùnrin Alberto Libombo tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Mozambique sọ pé: “Inú wa dùn láti rí ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí àwọn ará wa ní láti ṣèrànwọ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ìlú Mozambique ń bá ètò lọ láti pèsè oúnjẹ àti bí wọ́n á ṣe ṣàtúnṣe tàbí ṣàtúnkọ́ àwọn ilé tó ti bàjẹ́. Àá máa bá a lọ láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa pèsè ìtùnú nípa tẹ̀mí àti láti máa ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣẹ̀ sí.”

Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní àgbègbè Chiromo ni wọ́n lò fún ìgbà díẹ̀ láti pín àwọn nǹkan tí wọ́n kó wá.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000

Mozambique: Alberto Libombo, tel. +258 21 450 500