Ní June 29, 2017, ilé ẹjọ́ kan lórílẹ̀-èdè Kazakhstan pàṣẹ pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Almaty, ní Kazakhstan, dáwọ́ iṣẹ́ dúró fún oṣù mẹ́ta, wọ́n sì bu owó ìtanràn gọbọi lé wọn. Owó ọ̀hún tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún kan àti méje [2,107] owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Ohun tó mú kí ilé ẹjọ́ náà ṣe ìpinnu yìí lohun tó ṣẹlẹ̀ ní May 17, 2017. Lọ́jọ́ yẹn, àwọn aláṣẹ lọ tú ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, èyí sì pe èrò lé ọ́fíìsì náà. Àwọn agbófinró tó tó ogójì [40] ló ya wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, àwọn kan tiẹ̀ bojú nínú wọn. Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò láti fẹjọ́ sùn torí ohun táwọn aláṣẹ ṣe yìí.

Nígbà tó di June 5, 2017, àwọn ọlọ́pàá wá yẹ ẹ̀ka ọ́fíìsì náà wò, àwọn aláṣẹ sì sọ pé àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ káwọn rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí rú àwọn òfin kan. Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ kọ́ ló rí, torí pé kì í tiẹ̀ ṣe bó ṣe wà nínú òfin làwọn ọlọ́pàá náà ṣe ṣàyẹ̀wò ọ̀hún.

Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Kazakhstan yìí rán wa létí ohun táwọn ọlọ́pàá ń fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, tí ìjọba ti fòfin de iṣẹ́ wọn, àti ẹ̀tanú ẹ̀sìn táwọn èèyàn ń ṣe sí wọn. Tó bá di July 14, 2017, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ohun tí ilé ẹjọ́ sọ ní June 29 yìí.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Kazakhstan: Bekzat Smagulov, +7-747-671-45-01