Ní Wednesday, January 18, 2017, àjálù ńlá kan wáyé ní àgbègbè Abruzzo, ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Ítálì. Yìnyín ya bo òtẹ́ẹ̀lì kan mọ́lẹ̀, níbi táwọn èèyàn ti ń gbafẹ́, ó sì tó ọgbọ̀n [30] èèyàn tó wà nínú òtẹ́ẹ̀lì náà. Àgbègbè yìí kan náà ni ìmìtìtì ilẹ̀ tó le gan-an ti wáyé lóṣù August, ọdún tó kọjá. Kí yìnyín yẹn tó ya, ìmìtìtì ilẹ̀ tó le ti kọ́kọ́ wáyé lẹ́ẹ̀mẹ́rin lágbègbè yẹn, ọjọ́ kan náà sì ni mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣẹlẹ̀. Láti ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú ìgbà yẹn sì ni òjò yìnyín ti ń rọ̀ gidigidi, irú ẹ̀ kì í sì í sábà ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀. Òjò yìnyín yẹn ń mú kó túbọ̀ nira láti gbẹ̀mí àwọn èèyàn là níbi tí àjálù yìí ti wáyé, ọ̀pọ̀ ìlú ló sì wà ní àdádó, tí wọn ò ní iná mànàmáná.

Ìròyìn tá a gbọ́ látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ítálì ni pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò kú, ìkankan nínú wọn ò sì fara pa yánnayànna. Àmọ́ wọ́n ń sapá láti kàn sí ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbi tí àjálù náà ti rinlẹ̀ jù, ìyẹn níbi tí ìmìtìtì ilẹ̀ ti wáyé, tí òjò yìnyín sì ti rọ àrọ̀ọ̀rọ̀dá. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ alàgbà lágbègbè yẹn ti ń fún àwọn èèyàn lóúnjẹ, omi, igi ìdáná àtàwọn nǹkan pàtàkì míì tí wọ́n nílò. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bójú tó ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì ń pèsè ìrànwọ́ táwọn èèyàn nílò láfikún sí èyí táwọn alàgbà ń ṣe.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Ítálì: Christian Di Blasio, +39-06-872941