ÌLÚ RÓÒMÙ—Gbogbo oṣù September ọdún 2016 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi pín ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó dá lórí ìtùnú. Kókó iwájú ìwé ìròyìn náà ni “Ibo Lo Ti Lè Rí Ìtùnú?”, òun ni ìwàásù àkànṣe táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe kárí ayé lóṣù yẹn dá lé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń sapá gidigidi láti fi Bíbélì tu àwọn èèyàn nínú ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Ítálì, torí ìmìtìtì ilẹ̀ tó le gan-an wáyé níbẹ̀ ní August 24, 2016, ó sì rinlẹ̀ gan-an ní àgbègbè Lazio, Marche àti Umbria. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] èèyàn ni ẹ̀mí wọn lọ sí i, ó sì ba ilé àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] jẹ́.

Christian Di Blasio, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé: “Torí ká lè tu oríṣiríṣi èèyàn tó ń gbé ní gbogbo orílẹ̀-èdè nínú la ṣe ṣètò láti wàásù lọ́nà àkànṣe lóṣù yìí. Àmọ́ ní Ítálì ńbí, a dìídì fún àwọn tí ìmìtìtì ilẹ̀ ṣe ní jàǹbá láfiyèsí torí ìṣòro tí wọ́n ń bá fínra, títí kan àwọn tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù yìí.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá ẹnì kan tí àjálù yìí ṣẹlẹ̀ sí nílùú Amatrice sọ̀rọ̀, ìlú yìí làwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí ti pọ̀ jù.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ló wà níbi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀, kò sí Ẹlẹ́rìí kankan tó kú tàbí tó fara pa yánnayànna. Àmọ́ mẹ́ta nínú ilé wọn ló bà jẹ́ kọjá àtúnṣe, àwọn ilé míì sì bà jẹ́ díẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Di Blasio jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí ilé wọn bà jẹ́ tún yọ̀ǹda ara wọn láti fi ìwé ìròyìn tá à ń pín yẹn tu àwọn aládùúgbò wọn nínú. Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìmìtìtì ilẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ rí níbi tí wọ́n ń gbé yọ̀ǹda láti lọ bá àwọn tí àjálù dé bá yìí sọ̀rọ̀. Ọ̀gbẹ́ni Di Blasio sọ pé: “Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn yìí sọ pé ọ̀rọ̀ Bíbélì ló gbé wọn ró, tó sì tù wọ́n nínú, àwọn náà wá fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè tu àwọn èèyàn tí àjálù dé bá láwùjọ nínú.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Ítálì: Christian Di Blasio, 39-06-872941