Láàárọ̀ ọjọ́ Wednesday, December 7, ìmìtìtì ilẹ̀ tó le wáyé ní apá àríwá etí òkun ní erékùṣù Sumatra lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Ẹ̀rí wà pé àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ni ẹ̀mí wọn ti lọ sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sì fara pa.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Jakarta ti jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ti kàn sí gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè náà, kò sí èyí tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ìkankan nínú wọn ò sì fara pa. Bákan náà, ìkankan nínú ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn ò bà jẹ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè yẹn ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tu àwọn aládùúgbò wọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí pa lára nínú, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Indonéṣíà: Tom Van Leemputten, +62-813-4527-1974