Omi àti ẹrẹ̀ kún inú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Copiapó.

SANTIAGO, Chile—Ní March 25, 2015, àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò tó wáyé ní àgbègbè Atacama ní àríwá orílẹ̀-èdè Chile, mú kí ẹrẹ̀ ya wọ̀lú, ó sì tún fa omíyalé. Èyí ni ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé tó tíì burú jù lọ láti ọgọ́rin [80] ọdún sẹ́yìn. Ó lé ní ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] èèyàn tí àjálù náà kàn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn ni kò ní ilé mọ́ tí wọ́n sì kó wọn lọ sí ilé tí wọ́n ti lè tọ́jú wọn. Ó kéré tán, èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló ti kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Chile ròyìn pé kò sí Ẹlẹ́rìí kankan tó kú tàbí tó fara pa gan-an. Àmọ́ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí méje ló bà jẹ́ kọjá àtúnṣe, tí ọ̀pọ̀ ilé míì sì bà jẹ́ díẹ̀. Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ìyẹn ibi tá a ti ń jọ́sìn, bàjẹ́ pàtápàtá, àwọn méjì míì sì bàjẹ́ díẹ̀.

Àwọn ohun ìní tó bà jẹ́ nílùú Diego de Almagro, omíyalé náà ba ìlú yìí jẹ́ gan-an.

Ìlú Copiapó wà lára àwọn ìlú ti omíyalé náà ti ṣọṣẹ́ gan-an, níbẹ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò àwọn tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù láti gba ìsọfúnni nípa ohun tó bà jẹ́ àti láti ṣàtúnṣe wọn. Wọ́n tún rán aṣojú láti ẹ̀ká ọ̀fíìsì lọ sí àwọn àgbègbè tí àjálù ti wáyé, kó lè pèsè ìrànwọ́ tí wọ́n nílò kó sì tún fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ nínú. Àwọn Ẹlẹ́rìí láti ìlú Antofagasta, Arica, Calama, Caldera, Iquique, àti La Serena fi àwọn ohun èlò ránṣẹ́ sí àwọn olùjọ́sìn ẹlẹ́gbẹ láìjáfara.

Àwọn Ẹlẹ́rìí kó àwọn ohun èlò jọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó wà nílùú Alto Hospicio kí wọ́n tó kó o lọ sí àwọ̀n àgbègbè tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀.

Jason Reed, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Chile, sọ pé: “Àánú àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí ṣe wá gan-an, àwọn ìgbìmọ̀ tá a ṣètò láti ṣèrànwọ́ sí ti múra tán láti palẹ̀ ìdọ́tí mọ́, kí wọ́n sì ṣàtúnṣe ilé àwọn ará wa tó bà jẹ́. A tún ń sapá láti tu gbogbo àwọn tí àjálù omíyalé náà ṣẹlẹ̀ sí nínú, ká sì fún wọn ní ìṣìrí.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000

Chile: Jason Reed, tẹlifóònù +56 2 2428 2600