Ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní àádóje [130] ni ò lè pa dà sílé wọn lẹ́yìn tí wọ́n lọ sí àpéjọ àgbègbè wọn ní July 7-9, 2017 torí iná tó ń runlé rùnnà tó ti gbalẹ̀ kan níbì kan tó wà ní gúúsù ìlú Prince George, ní British Columbia. Àwọn aláṣẹ ti sọ fáwọn aráàlú pé kí wọ́n kó kúrò lágbègbè náà.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Ontario lórílẹ̀-èdè Kánádà ti ṣètò ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ lásìkò àjálù pé kí wọ́n pèsè ilé àti oúnjẹ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Ilé àpérò tí wọ́n ń pè ní CN Centre làwọn Ẹlẹ́rìí bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] ti ṣe àpéjọ àgbègbè wọn, àwọn aláṣẹ tó ń bójú tó ibẹ̀ sì ti gbà kí wọ́n gbé àwọn mọ́tò ńlá wọn tó nílé lẹ́yìn sínú ọgbà ilé náà, káwọn kan nínú wọn ṣì lè máa ríbi sùn.

Láti oríléeṣẹ́ wa ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò bá a ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá, wọ́n ń lo owó táwọn èèyàn fi ń ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Kánádà: Matthieu Rozon, +1-905-873-4100