Ní Tuesday, March 28, 2017, ìjì lílé kan tí wọ́n pè ní Tropical Cyclone Debbie jà ní ilẹ̀ tó wà létíkun ní àríwá ìpínlẹ̀ Queensland àtàwọn erékùṣù tó wà nítòsí ibẹ̀, atẹ́gùn líle sì ń fẹ́ níbẹ̀ ṣáá. Ìjì yẹn le gan-an, ó wó igi, ó ba ilé jẹ́, ó sì wó àwọn ọkọ̀ ojú omi mọ́lẹ̀ láwọn ìlú tó wà létíkun. Ìjì Cyclone Debbie yìí tún mú kí omi yalé gan-an láwọn ìlú tó wà ní gúúsù ìpínlẹ̀ Queensland àti àríwá ìpínlẹ̀ New South Wales, ó sì ba iná mọ̀nàmọ́ná tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò jẹ́.

Ìròyìn tó kọ́kọ́ dé etí wa ni pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò fara pa yánnayànna, ìkankan nínú wọn ò sì kú. Àmọ́ ìjì náà ba ilé ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́, ilé kan tiẹ̀ bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Gbọ̀ngàn Ìjọba (ìyẹn, ibi ìjọsìn) méjì ló tún bà jẹ́.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà ṣètò ìgbìmọ̀ méjì tó ń ṣètò ìrànwọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó ọ̀rọ̀ pàjáwìrì, kí wọ́n sì máa gbé jẹnẹrétọ̀, oúnjẹ àti omi lọ fún àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn àgbègbè náà sì ń ran àwọn ará wọn lọ́wọ́, wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì gbé wọn ró, wọ́n sì ń tù wọ́n nínú.

Láti oríléeṣẹ́ wa ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bójú tó bá a ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí, wọ́n ń lò lára owó táwọn èèyàn fi ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Australasia: Rodney Spinks, +61-2-9829-5600