Ìlú BUENOS AIRES, lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà—Láti March 29, 2017 títí di April  9, 2017, òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá rọ̀, ó sì mú kí omi yalé láwọn àgbègbè kan lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà, bíi Buenos Aires, Chaco, Chubut, Catamarca, Jujuy, Misiones, La Pampa, Salta, San Juan, Santa Cruz, Santa Fe, Santiago del Estero àti Tucumán. Ìròyìn tá a gbọ́ látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà ni pé ìkankan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ, ìkankan nínú wọn ò sì fara pa.

Òjò yẹn mú kí ìjì jà, àgbègbè Chubut àti Salta sì ni ìjì yẹn ti le jù. Nílùú Comodoro Rivadavia, ní Chubut, ṣe ni gbogbo òjò tó yẹ kó rọ̀ láàárín ọdún kan fi ọjọ́ mélòó kan rọ̀, ó sì gba pé kí ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọgọ́ta [60] kúrò nílé wọn. Bákan náà, ibi ìjọsìn méjì, tí wọ́n tún ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ló bà jẹ́, ọ̀kan ní àgbègbè Chubut àti ọ̀kan ní àgbègbè Salta. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà ti ṣètò ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù sí àgbègbè méjèèjì kí wọ́n lè máa ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí, à ń retí pé kí wọ́n máa báṣẹ́ lọ fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Ajẹntínà: Omar A. Sánchez, +54-11-3220-5900