Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Lobito tí ẹrọ̀fọ̀ tó ga tó àádọ́rin sẹ̀ǹtímítà rọ́ sínú rẹ̀.

LUANDA, Àǹgólà—Àgbáàràgbá òjò tó bẹ̀rẹ̀ ní March 11, 2015 ṣokùnfa omíyalé tó gbẹ̀mí èèyàn márùnlélọ́gọ́rin [85], tó sì ba ilé mọ́kàndínlọ́gọ́fà [119] jẹ́ ní agbègbè Benguela. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà ni agbègbè yìí fi jìnnà sí olú ìlú Luanda. Ẹ̀ka ọ́fíísì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Àǹgólà sọ pé kò sí Ẹlẹ́rìí kankan tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àmọ́ ilé mọ́kànlá tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí ni jàǹbá náà bà jẹ́. Àgbàrá náà ba Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ilé ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Lobito jẹ́.

Láàárọ̀ ọjọ́ tó tẹ̀ lé ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àwa Ẹlẹ́rìí ṣètò ìgbìmọ̀ kan tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù láti ṣàyẹ̀wò gbogbo ohun tó bà jẹ́, kí wọ́n sì ṣètò bí wọ́n á ṣe ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù náà bá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pèsè ìrànwọ́ fáwọn arákùnrin wọn tó wà lágbègbè yìí àtàwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Lobito, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ṣiṣẹ́ kára láti gbá ẹrọ̀fọ̀ tó ga tó àádọ́rin [70] sẹ̀ǹtímítà síta. Wọ́n tún ṣe àwọn àtúnṣe míì lásìkò tó fi mú kó ṣeé ṣe láti ṣe ọ̀kan lára àwọn ìpàdé àkànṣe tí wọ́n ṣètò ní òpin ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé àjálù náà. Àwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Àǹgólà rìnrìn àjò láti Luanda fún ìpàdé náà, wọ́n tu àwọn ará nínú, wọ́n sì fún wọn níṣìírí.

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà ṣàtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó bà jẹ́ ní Lobito.

Todd Peckham tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Àǹgólà sọ pé: “À ń kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ti àjálù omíyalé yìí bá. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Àǹgólà yóò ṣì máa bójú tó ètò ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá, wọ́n á sì máa ṣètìlẹyìn fáwọn tó wà lágbègbè náà.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000

Àǹgólà: Todd Peckham, tẹlifóònù +244 222 460 192