Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Èyí Tó Wà Fáwọn Oníròyìn

SOUTH KOREA

Ẹnì Kan Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun Ń Fayọ̀ Retí Ìgbẹ́jọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ

Tó bá di August 30, 2018, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní South Korea máa ṣe àpérò kan lórí ohun tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba sọ pé kí wọ́n ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

RUSSIA

Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Gbẹ́sẹ̀ Lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Tẹ́lẹ̀

Kí ẹjọ́ kọ̀tẹ́milọ́rùn tó bẹ̀rẹ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Ìlú St. Petersburg, akọ̀ròyìn kan, onímọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kan àtàwọn agbẹjọ́rò méjì túdìí àṣírí àìṣèdájọ́ òdodo tó wà nínú bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe gba ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tẹ́lẹ̀.

ITALY

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Luca P. Weltert, M.D.

“Èrò àwọn dókítà nípa fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára àti ọwọ́ tí wọ́n fi mú un ti wá yàtọ̀ gan-an báyìí. Ó ti wá ṣe kedere pé wọn kì í fẹ́ fa ẹ̀jẹ̀ síni lára mọ́, kì í wá ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń tọ́jú nìkan o, àtàwọn míì kárí ayé. Ìdí sì ni pé ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló ti wà báyìí pé àwọn tí wọn ò fa ẹ̀jẹ̀ sí lára máa ń ṣe dáadáa lẹ́yìn ìtọ́jú ju àwọn tó gbẹ̀jẹ̀ lọ.”

ITALY

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Ọ̀jọ̀gbọ́n Antonio D. Pinna, M.D.

“Mi ò rò pé ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn jẹ́ ìṣòro rárá. Torí pé, àwọn kan tí kì í ṣe ajẹ́rìí pàápàá kì í fẹ́ gbẹ̀jẹ̀.”

ITALY

Àpérò Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Wáyé ní Yunifásítì Padua Láti Jíròrò Ìtẹ̀síwájú Tó Ti Bá Ọ̀rọ̀ Títọ́jú Aláìsàn Láìlo Ẹ̀jẹ̀

Ọ̀pọ̀ ló gbà pé fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára ò léwu, wọ́n sì gbà pé òun nìkan lọ̀nà àbáyọ fáwọn aláìsàn tí ọ̀rọ̀ ìtọ́jú wọn tàbí iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fẹ́ ṣe díjú. Àmọ́ púpọ̀ nínú àwọn tó sọ̀rọ̀ níbi àpérò náà ni kò fara mọ́ èrò yẹn.

ITALY

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Ọ̀jọ̀gbọ́n Massimo P. Franchi, M.D.

“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an lẹ́nu iṣẹ́ mi débi pé mo ti wá mọ àwọn ọ̀nà ti mo lè gbà tọ́jú aláìsàn lọ́nà ti ìgbàlódé láìlo ẹ̀jẹ̀.”

RUSSIA

Àwọn Aláṣẹ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Fẹ́ Gbẹ́sẹ̀ Lé Ilé Tó Jẹ́ ti Àjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Ilé Ẹjọ́ Saint Petersburg máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ kọ́kọ́ dá pé kí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì àtijọ́ tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.

ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àpéjọ Àgbègbè Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Ṣe Lọ́dọọdún Máa Bẹ̀rẹ̀ ní May 2018

Kó tó dìgbà yẹn, kárí ayé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ké sí gbogbo èèyàn pé kí wọ́n wá síbi àpéjọ náà lọ́fẹ̀ẹ́.

ISRAEL

Wọ́n Fi Ohun Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Là Kọjá Nígbà Ìjọba Nazi Hàn Níbi Ìpàtẹ Kan ní Tel Aviv

Wọ́n ṣe ìpàtẹ kan sí Tel Aviv káwọn èèyàn bàa lè mọ ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà là kọjá nígbà ìjọba nazi.

BOLIVIA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Àmì Ẹ̀yẹ Torí Bí Wọ́n Ṣe Gbé Àṣà Ìbílẹ̀ Bòlífíà Yọ Níbi Àpéjọ Àgbègbè Wọn

Wọ́n fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lámì ẹ̀yẹ torí àtúnṣe ńlá tí wọ́n ṣe síbi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ náà, tí wọ́n sì pàtẹ àwọn ohun tó jẹ mọ́ àṣà ìbílẹ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Bòlífíà.

FINLAND

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Pa dà Sẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Níbi Térò Pọ̀ Sí Ní Turku lórílẹ̀-èdè Finland

Àwọn afẹ̀míṣòfò pa èèyàn ní ìlú Turku lórílẹ̀-èdè Finland ní August 18, 2017. Àmọ́ ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, inú àwọn òṣìṣẹ́ ìlú dùn gan-an láti rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní gbàgede ọjà yẹn.