Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá fẹ́ gbàtọ́jú nílé ìwòsàn, ìtọ́jú tí kò ní la gbígba ẹ̀jẹ̀ sára lọ ni wọ́n máa ń fẹ́. Wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti gba irú ìtọ́jú tí wọ́n bá fẹ́, ìtọ́jú tó dáa jù lọ sì ni wọ́n máa ń fẹ́ fún ara wọn àtàwọn ọmọ wọn.