Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti kóra jọ lómìnira pẹ̀lú àwọn ará wọn. Tí wọ́n bá kóra jọ láti jọ́sìn, wọ́n máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹnikẹ́ni ló sì lè wá bá wọn jọ́sìn.