Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lórílẹ̀-èdè Uzbekistan kí orílẹ̀-èdè náà tó gbòmìnira lọ́dún 1991. Ní 1992, orílẹ̀-èdè Uzbekistan ṣòfin tó fọwọ́ sí i pé àwọn aráàlú ní àwọn ẹ̀tọ́ kan. Àmọ́ ìjọba kì í sábà tẹ̀ lé òfin yẹn délẹ̀délẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn.

Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Uzbekistan ṣì ń kọ̀ láti forúkọ gbogbo ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ìjọ kan ṣoṣo ni wọ́n forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ nílùú Chirchik. * Torí náà, àwọn aláṣẹ sọ pé ìpàdé èyíkéyìí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ṣe níbòmíì yàtọ̀ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Chirchik ò bófin mu. Táwọn Ẹlẹ́rìí bá lọ ṣèpàdé níbòmíì, kódà kó jẹ́ inú ilé ara wọn, ṣe làwọn ọlọ́pàá máa ń da ibẹ̀ rú. Wọ́n máa ń mú àwọn tó bá wà níbẹ̀, wọ́n á sì gba àwọn ohun ìní wọn àtàwọn ìwé ẹ̀sìn wọn. Àwọn aláṣẹ máa ń ti àwọn Ẹlẹ́rìí kan mọ́lé fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, wọ́n á lù wọ́n, wọ́n á sì máa sọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ sí wọn. Ṣe ni wọ́n bu owó ìtanràn gọbọi lé àwọn Ẹlẹ́rìí kan, ilé ẹjọ́ dá wọn lẹ́bi pé ọ̀daràn ni wọ́n, wọ́n sì rán wọn lọ sẹ́wọ̀n torí wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn wọn. Bí ìjọba ò ṣe gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ yìí ti jẹ́ kí wọ́n mú àwọn èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ yìí ní ọ̀daràn, kí wọ́n sì fòfin de ẹ̀sìn wọn tí wọ́n ń ṣe ní ìrọwọ́rọsẹ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò yéé pààrà ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, wọ́n ṣì fẹ́ kí wọ́n forúkọ àwọn ìjọ wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin jákèjádò orílẹ̀-èdè Uzbekistan, pàápàá nílùú Tashkent. Tí ìjọba bá fọwọ́ sí i, ó máa jẹ́ kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tanú táwọn èèyàn ń ṣe sí wọn déwọ̀n àyè kan, á sì jẹ́ kí wọ́n lè fọ̀wọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀ wọ́n pé wọ́n lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn.

^ ìpínrọ̀ 3 1994 ni wọ́n kọ́kọ́ forúkọ sílẹ̀, wọ́n wá tún un ṣe ní 1999.