Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé
-
FEBRUARY 19, 2009 — Àwọn aláṣẹ ò fọwọ́ sí ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí kọ láti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Tashkent, ẹ̀ẹ̀kẹrìndínlógún tí wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀ rèé. Wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ látọdún 1997, 1998, 2000, 2001, 2003, 2004, 2005 àti 2006
-
AUGUST 24, 2006 — Lẹ́yìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ nílùú Fergana, ìjọba fagi lé e
-
AUGUST 1999 — Ìjọba tún orúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Chirchik àti Fergana
-
MAY 1, 1998 — Ìjọba ṣòfin lórí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn, ó sì gba káwọn ẹlẹ́sìn wá tún orúkọ ẹ̀sìn wọn fi sílẹ̀ lábẹ́ òfin
-
DECEMBER 1996 — Àwọn Ẹlẹ́rìí kọ̀wé síjọba láti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Tashkent, àmọ́ ìjọba ò fọwọ́ sí i
-
DECEMBER 17, 1994 — Ìjọba forúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Chirchik àti Fergana
-
DECEMBER 8, 1992 — Ìjọba tuntun ṣòfin tó fọwọ́ sí àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó ṣe pàtàkì fáwọn aráàlú
-
SEPTEMBER 1, 1991 — Orílẹ̀-èdè Uzbekistan gbòmìnira
-
1960’s — Ọdún yìí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ ròyìn iṣẹ́ wọn nílùú Angren àti Chirchik