Ojoojúmọ́ làwọn èèyàn tó ń gbé ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Ukraine ń fojú winá ohun tó ń mú káyé dojú rú fún wọn, tó ń dẹ́rù bà wọ́n, tí kò sì jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀. Ìjà tó ń wáyé lágbègbè náà ò tún jẹ́ kí ọkàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà balẹ̀. Kì í ṣe bí ẹ̀mí àwọn èèyàn tó wà lágbègbè yìí ṣe wà nínú ewu nìkan nìṣòro, àmọ́ wọ́n tún ń ṣe ẹ̀tanú ẹ̀sìn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ọkùnrin tó dira ogun ti gba àwọn Gbọ̀ngan Ìjọba (ìyẹn ilé ìjọsìn) kan mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́. Wọ́n ti sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí pé ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì nìkan lòfin fọwọ́ sí káwọn èèyàn máa ṣe, wọ́n sì sọ pé àwọn máa ṣe é táwọn èèyàn ò fi ní “gbúròó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́” ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Ukraine.

Wọ́n Fipá Gba Gbọ̀ngàn Ìjọba

Láàárín June 2014 àti November 2016, àwùjọ àwọn kan tó dira ogun ti fipá gba Gbọ̀ngàn Ìjọba méjìdínlógún [18], wọ́n fi àwọn kan ṣe bárékè wọn, wọ́n sì ń lo àwọn míì fún iṣẹ́ wọn. Ìgbà tí ìjà tó ń wáyé lágbègbè náà ń le sí i lọ́dún 2014 ni wọ́n ti fipá gba èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, àmọ́ wọ́n tún gba àwọn kan láìpẹ́ yìí.

Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní No. 9 ládùúgbò Simferopolska, nílùú Horlivka tí wọ́n tú, tí wọ́n sì kẹ́rù inú ẹ̀

Láàárọ̀ ọjọ́ Friday, July 22, 2016, àwọn Ẹlẹ́rìí kan nílùú Horlivka kóra jọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní No. 105-A ládùúgbò Vitchyzniana láti ṣèjọsìn, ni àwọn ọkùnrin kan tó dira ogun bá wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, wọ́n sì ní kí gbogbo èèyàn jáde lójú ẹsẹ̀. Àwọn ọkùnrin náà tú gbogbo ilé náà, wọ́n sì kó gbogbo àga, tábìlì àtàwọn ohun tí wọ́n ń lò níbẹ̀ kúrò. Wọ́n ti kọ́kọ́ fipá gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí kan náà ní November 29, 2014, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi pa á tì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ti pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpàdé ẹ̀sìn wọn nínú ilé ìjọsìn yìí kó tó di pé wọ́n tún fipá gbà á mọ́ wọn lọ́wọ́ ní July 22.

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, àwọn ọkùnrin tó dira ogun wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba míì tó wà ní No. 9  ládùúgbò Simferopolska, nílùú Horlivka. Àwọn ọkùnrin náà kó gbogbo ohun tó wà nínú ilé náà, títí kan àwọn ẹ̀rọ tó ń mú ilé gbóná, wọ́n sì yọ ọgbà tí wọ́n ṣe sí ilé náà yí ká. Ó wá di pé kí àwọn ìjọ tó ń ṣèpàdé nínú ilé yìí tẹ́lẹ̀ ṣe àwọn ètò míì kí wọ́n lè máa kóra jọ láti jọ́sìn.

Wọn Ò Yéé Pàdé Pọ̀ Láti Jọ́sìn

Ṣe làwọn ìjọ kan tí wọ́n fipá gba Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ń lò pín ara wọn sí àwùjọ kéékèèké kí wọ́n lè máa pàdé láìfu àwọn ológun lára. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì máa ń rìnrìn àjò lọ jọ́sìn láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba míì tí ò sí níbi tí wàhálà ti ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà, kì í rọrùn fún wọn láti débẹ̀, ó sì ń ná wọn lówó. Àwọn tí ọjọ́ ogbó tàbí àìlera ò jẹ́ kí wọ́n lè rìnrìn àjò máa ń fi tẹlifóònù gbọ́ ohun tó ń lọ nípàdé.

Ìjà tó ń wáyé àtàwọn ìnira míì ń mú kó túbọ̀ nira láti kóra jọ fún ìjọsìn. Illia Kobel, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ukraine sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wọn tó ń gbé nítòsí àgbègbè tó wà láàárín àwọn ẹgbẹ́ tó ń jà ò ní ìfọ̀kànbalẹ̀, ẹ̀rù sì máa ń bà wọ́n torí ìró ìbọn àti bọ́ǹbù tó máa ń dún léraléra. Nǹkan ò tún ṣẹnuure fún wọn torí pé gbogbo nǹkan ló ń wọ́n, bẹ́ẹ̀, owó ò fi bẹ́ẹ̀ wọlé fún wọn. Àmọ́ láìka àwọn ìṣòro yìí sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò yéé pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wọn láti jọ́sìn.”

Awọn Ẹlẹ́rìí Pa Dà Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Kan

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn pé àwọn ti lè máa pa dà jọ́sìn nínú mẹ́fà lára àwọn ilé tí àwọn ológun fipá gbà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ba àwọn ilé yẹn jẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò yẹn jọ pawọ́ pọ̀ tún un ṣe kó lè rí bó ṣe yẹ tí wọ́n bá fẹ́ máa lò ó fún ìjọsìn. Ilé míì wà yàtọ̀ sí àwọn mẹ́fà yẹn tó bà jẹ́ gan-an débi pé wọn ò tíì lè máa lò.

Ìjọ kan tí wọ́n lé kúrò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ń lò lágbègbè Luhansk ní September 2014 ti bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà jọ́sìn níbẹ̀ lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan. Anatoliy Danko tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ yẹn sọ bó ṣe rí lára ọ̀pọ̀ àwọn ará, ó ní: “Irú àsìkò yìí la máa ń mọ̀ pé ọmọ ìyá wa làwọn tá a jọ wà nínú ìjọ. A ti pa dà sílé lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ìyá wa báyìí lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tá ò fi sí pa pọ̀.”

Wọn Ò Dá sí Ogun

Kárí ayé làwọn èèyàn ti mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú àti ogun, wọn kì í gbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni. Tàwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Ukraine náà ò yàtọ̀. Wọ́n ń wọ̀nà fún ìgbà tí àwọn pẹ̀lú ìdílé wọn àtàwọn aládùúgbò á lè máa gbé lálàáfíà, tí wọ́n á sì lè máa ṣe ẹ̀sìn wọn láìsí ìdíwọ́.