Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

UKRAINE

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Ukraine

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Ukraine

Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà ní orílẹ̀-èdè Ukraine. February 28, 1991 ni wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, kété kí orílẹ̀-èdè Ukraine tó gbòmìnira.

Ìjọba Násì àti ti Soviet fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbolẹ̀ gan-an lórílẹ̀-èdè Ukraine. Ní April 8, 1951, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún kan [6,100] ni àwọn aláṣẹ ìjọba Soviet lé kúrò ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Ukraine lọ sí ìlú Siberia. Àmọ́ nǹkan sàn díẹ̀ ní June 1965, lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Ukraine sọ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ló wà nínú ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í ṣe ohun tó ta ko ìjọba Soviet. Tẹ́lẹ̀, àwọn aláṣẹ máa ń mú àwọn tó bá ń ka ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí, àmọ́ wọ́n dáwọ́ dúró lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ṣe ìkéde yìí. Síbẹ̀, wọ́n ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì. Ní September 1965, ìjọba dá gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n lé lọ sí Siberia lọ́dún 1951 sílẹ̀, àmọ́ wọn ò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ nínú wọn pa dà síbi tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀. Títí di nǹkan bí ọdún 1980 sí 1984, wọ́n ṣì ń gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gidigidi.

Lóde òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira láti pàdé fún ìjọsìn, kí wọ́n sì máa wàásù fáwọn èèyàn láìsí pé àwọn aláṣẹ ń yọ wọ́n lẹ́nu. Àmọ́ àwọn èèyàn máa ń ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí níkà torí pé wọ́n kórìíra wọn. Ṣe ni wọ́n máa ń lu àwọn Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n sì ń ba ilé ìjọsìn wọn jẹ́, àmọ́ àwọn aláṣẹ kì í fi bẹ́ẹ̀ gbèjà wọn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í sì í pe àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ibi yìí lẹ́jọ́. Àwọn jàǹdùkú yìí sì ń mú un jẹ torí pé àwọn aláṣẹ ń wò wọ́n níran, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà. Gbogbo èyí ti wá fi kún ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà.