Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

SEPTEMBER 14, 2016
TURKMENISTAN

Àwọn Aláṣẹ Ìlú Ashgabad Rán Mansur Masharipov Lọ Sẹ́wọ̀n Láì Mọwọ́ Mẹsẹ̀

Àwọn Aláṣẹ Ìlú Ashgabad Rán Mansur Masharipov Lọ Sẹ́wọ̀n Láì Mọwọ́ Mẹsẹ̀

Àwọn agbófinró mú Ọ̀gbẹ́ni Mansur Masharipov ní June 30, 2016, nínú ọgbà kan tó wà nílùú Ashgabad, lórílẹ̀-èdè Turkmenistan. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, àtìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2014 làwọn ọlọ́pàá sì ti ń dọdẹ rẹ̀ kiri torí pé ó ń jọ́sìn Ọlọ́run. Wọ́n fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Masharipov, tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n [32] pé ó lu ọlọ́pàá kan, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún ló lù ú nílùkulù. Wọ́n ti fìyà jẹ Ọ̀gbẹ́ni Masharipov rí, kódà wọ́n ṣe é bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú torí pé ó ń jọ́sìn Ọlọ́run láìbá ẹnikẹ́ni fa wàhálà. Ní August 18, 2016, ilé ẹjọ́ kan lórílẹ̀-èdè Turkmenistan rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba. Àmọ́ Ọ̀gbẹ́ni Masharipov ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.