Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Aibek Salayev, Matkarim Aminov àti Bahram Shamuradov wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n dá sílẹ̀

NOVEMBER 13, 2014
TURKMENISTAN

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Turkmenistan Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Sílẹ̀

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Turkmenistan Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Sílẹ̀

Ìgbà ọ̀tun dé! Ààrẹ Gurbanguly Berdimuhamedov dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Turkmenistan. Wọ́n wà lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n míì tí ìjọba dá sílẹ̀ ní October 22, 2014. Torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ni wọ́n ṣe fi mẹ́fà nínú wọn sẹ́wọ̀n, wọ́n sì lọ́ ẹ̀sùn mọ́ àwọn méjì tó kù lẹ́sẹ̀ torí pé wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run, làwọn náà bá dèrò ẹ̀wọ̀n.

Merdan Amanov àti Pavel Paymov

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun yìí ò ju ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sí mẹ́tàlélógún [23] lọ, ọgbà ẹ̀wọ̀n Seydi Labor Colony tó wà ní aṣálẹ̀ Turkmen ni wọ́n sì fi wọ́n sí, tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àṣekára. Ibi tí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù wà ni wọ́n fi àwọn mẹ́rin lára wọn sí, àmọ́ ibi tí wọ́n ti ń fìyà pá àwọn ẹlẹ́wọ̀n lórí ni Matkarim Aminov àti Dovran Matyakubov wà, torí pé kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣẹ̀wọ̀n lórí ọ̀rọ̀ yìí nìyí. Ìyà jẹ àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí gan-an lẹ́wọ̀n, nǹkan ò sì fara rọ rárá níbẹ̀.

Aibek Salayev tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì [35] àti Bahram Shamuradov tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógójì [42] ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì yòókù tó wà lẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn tí wọ́n lọ́ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀, ọgbà ẹ̀wọ̀n Seydi ni wọ́n fi àwọn náà sí. Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin ni wọ́n rán àwọn méjèèjì lọ torí pé wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Yàtọ̀ sí pé ẹ̀sùn irọ́ tí wọ́n lọ́ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ sọ wọ́n dèrò ẹ̀wọ̀n, ṣe ni wọ́n tún fìyà pá wọn lórí níbẹ̀.

Amirlan Tolkachev

Ruslan Narkuliev nìkan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣì wà lẹ́wọ̀n ní orílẹ̀-èdè Turkmenistan. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan kí ìjọba tó dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀ ni wọ́n rán òun lọ sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun, ó sì ṣeé ṣe kí orúkọ tiẹ̀ máà tíì dé Ọ́fíìsì Ààrẹ nígbà tí wọ́n kéde pé wọ́n máa dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀. Àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ ti ń kàn sí àwọn aláṣẹ Turkmen kí wọ́n lè dá a sílẹ̀.

Ó wúni lórí gan-an pé Ààrẹ Berdimuhamedov gbé ìgbésẹ̀ akin yìí, ìyẹn bó ṣe dá àwọn mẹ́jọ tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sílẹ̀. Àwọn tó mọyì kéèyàn lómìnira ẹ̀sìn láwùjọ ń retí pé irú èyí la ó máa rí lórílẹ̀-èdè Turkmenistan, kí ìgbà ọ̀tun wọlé dé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa ṣe ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu láìsí ìbẹ̀rù pé ẹnikẹ́ni á yọ wọ́n lẹ́nu tàbí sọ wọ́n dèrò ẹ̀wọ̀n.