Nínú ìpinnu mẹ́wàá tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n sọ fún ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan pé kí wọ́n mú àdéhùn tí wọ́n tọwọ́ bọ̀ ṣẹ, pé àwọn ò ní fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àwọn aráàlú dù wọ́n. * Ọdún 2015 àti 2016 ni wọ́n gbé àwọn ìpinnu yìí jáde, wọ́n sọ pé ìjọba Turkmenistan ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun mọ́, wọ́n sì gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights tó wá látọ̀dọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, èyí tí ìjọba Turkmenistan ti tọwọ́ bọ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ń Wá Ojútùú

Ẹ̀sùn tí àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú wá ní September 2012 ló mú kí Ìgbìmọ̀ yìí ṣe àwọn ìpinnu yẹn. Ṣe ni ìjọba fìyà jẹ àwọn ọkùnrin náà torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Mẹ́sàn-án nínú wọn ni wọ́n ṣe bọ́ṣẹ ṣe ń ṣojú, ìròyìn tá a gbọ́ ni pé wọ́n máa ń lù wọ́n, wọ́n sì ń fìyà pá wọn lórí. Ibi tí wọ́n fi wọ́n sí lẹ́wọ̀n tún gbóná gan-an, ó dọ̀tí, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sì ń lo ibẹ̀ ti pọ̀ jù, èyí sì lè mú kí wọ́n kó àìsàn.

Gbogbo ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ náà ṣe fi hàn pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan ti fi “òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn” du àwọn ọkùnrin tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun yìí. Ní ti àwọn ọkùnrin mẹ́sàn-án tí wọ́n fìyà jẹ lẹ́wọ̀n, Ìgbìmọ̀ náà sọ pé ìjọba Turkmenistan ò “fọ̀wọ̀ [wọn] wọ̀ wọ́n, wọ́n sì hùwà àìdáa sí wọn” àti pé wọ́n “hùwà ìkà sí [wọn], wọ́n fìyà tí kò tọ́ jẹ wọ́n, ìyà tí wọ́n sì fi jẹ wọ́n yìí bù wọ́n kù, kò yẹ ọmọ èèyàn rárá.”

Ìgbìmọ̀ náà sọ pé kí ọ̀rọ̀ náà lè lójú, ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan gbọ́dọ̀ fagi lé gbogbo àkọsílẹ̀ tó bá wà pé ọ̀daràn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí, kí wọ́n sanwó gbà-máà-bínú fún wọn, kí wọ́n sì tún òfin ilẹ̀ wọn ṣe kí wọ́n má bàa “fi ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti kọ iṣẹ́ ológun dù wọ́n mọ́ rárá.” Ìgbìmọ̀ náà tún sọ fún ìjọba pé kí wọ́n ṣèwádìí dáadáa láìgbè sẹ́yìn ẹnì kankan nípa àwọn tí wọ́n fẹjọ́ wọn sùn pé wọ́n ń hùwà àìdáa sáwọn Ẹlẹ́rìí, kí wọ́n sì pe ẹnikẹ́ni tó bá jẹ̀bi lẹ́jọ́.

Lọ́dún 2013, àwọn ọkùnrin márùn-ún míì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí fẹjọ́ sun Ìgbìmọ̀ náà pé ìjọba fìyà jẹ àwọn torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ káwọn ṣiṣẹ́ ológun. Àwọn agbẹjọ́rò wọn ń retí pé ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ náà máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ wọn máa jọ ti àwọn mẹ́wàá àkọ́kọ́.

Wọ́n Fìyà Jẹ Navruz Nasyrlayev Gan-an Láìtọ́

Navruz Nasyrlayev

Ọ̀kan lára ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ náà ṣe, tó jáde ní July 15, 2016, dá lórí ọ̀rọ̀ Navruz Nasyrlayev. Nígbà tí ìjọba kọ́kọ́ pè é kó wá wọṣẹ́ ológun ní April 2009 lọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18], ó ṣàlàyé fáwọn aláṣẹ pé ẹ̀rí ọkàn ò ní jẹ́ kóun ṣe é. Àmọ́, ó sọ pé òun ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú. Wọ́n pa dà dá a lẹ́bi pé ó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjì ní ẹ̀wọ̀n LBK-12 nílùú Seydi. Nígbà tó wà níbẹ̀, léraléra ni wọ́n máa ń tì í mọ́nú yàrá kan tí wọ́n ti ń fìyà jẹ ẹ́, tí àwọn ẹ̀ṣọ́ kan tó fi nǹkan bojú á sì lù ú ní àlùbami.

Ní January 2012, lẹ́yìn oṣù kan tí wọ́n dá a sílẹ̀, wọ́n tún pe Ọ̀gbẹ́ni Nasyrlayev pé kó wá wọṣẹ́ ológun. Ṣe ló tún sọ fún wọn pé òun ṣe tán láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun, àmọ́ wọ́n dá a lẹ́bi, wọ́n sì tún rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjì míì lórí ẹ̀sùn kan náà. Lọ́tẹ̀ yìí, “ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ti ń ṣẹ́ni níṣẹ̀ẹ́” ni wọ́n fi sí, ipò nǹkan níbẹ̀ sì “burú kọjá sísọ.” Bíi ti tẹ́lẹ̀, ṣe ni àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n máa ń lù ú ní àlùbami, tí wọ́n sì máa ń fipá mú un láti ṣe iṣẹ́ tó ń rẹni nípò wálẹ̀.

Ìyà jẹ àwọn mọ̀lẹ́bí Ọ̀gbẹ́ni Nasyrlayev náà. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Ìgbìmọ̀ náà kọ̀wé sí ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan pé kí wọ́n ṣàlàyé ohun tó mú wọn máa fìyà tí kò tọ́ jẹ Ọ̀gbẹ́ni Nasyrlayev ni àwọn ọlọ́pàá wá ya bá àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ nílé ní ìlú Dashoguz. Wọ́n ṣe àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àtàwọn àlejò wọn ṣúkaṣùka, ó jọ pé ṣe ni wọ́n wá gbẹ̀san torí pé Ọ̀gbẹ́ni Nasyrlayev ti fẹjọ́ wọn sùn.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dá Ọ̀gbẹ́ni Nasyrlayev sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní May 2014, ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀wọ̀n tí wọ́n rán an lọ ò tíì tán lára ẹ̀. Ìgbìmọ̀ náà kíyè sí i pé wọ́n ti fìyà jẹ ẹ́ jù, àti pé ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n dá a lẹ́bi, tí wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́ lórí “ohun kan náà tó ti pinnu pé òun ò ní ṣe torí ẹ̀rí ọkàn.” Ohun tí Ìgbìmọ̀ náà fi parí ọ̀rọ̀ wọn nìyí: “Ohun tí [Ọ̀gbẹ́ni Nasyrlayev] gbà gbọ́ ló mú kó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun dandan . . . , bí wọ́n [sì] ṣe dá a lẹ́bi, tí wọ́n wá rán an lọ sẹ́wọ̀n fi hàn pé wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ lójú, ìyẹn òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti òmìnira ẹ̀sìn tó ní.”

Ṣé Ìjọba Turkmenistan Máa Yí Pa Dà Lórí Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣe Sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Lọ́dún 2012, nínú ìròyìn kan tó kọ́kọ́ jáde lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè Turkmenistan, Ìgbìmọ̀ náà rọ ìjọba pé kí wọ́n “jáwọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń pe gbogbo àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lẹ́jọ́, kí wọ́n sì dá àwọn tó wà lẹ́wọ̀n báyìí sílẹ̀.” Ìjọba Turkmenistan láwọn ti gbọ́, àmọ́ wọn ò ṣe gbogbo ohun tí Ìgbìmọ̀ náà sọ délẹ̀délẹ̀. Lóòótọ́, ní February 2015, wọ́n dá Ẹlẹ́rìí tó gbẹ̀yìn sí ẹ̀wọ̀n lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn àti iṣẹ́ ológun sílẹ̀. Látìgbà yẹn, wọn ò rán Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan lọ sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.

Àmọ́ o, ìjọba Turkmenistan ò yéé pe àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lẹ́jọ́, wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ta ko àdéhùn tí wọ́n bá ìjọba àpapọ̀ kárí ayé ṣe pé àwọn ò ní fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du àwọn aráàlú.

  • Láti apá ìparí ọdún 2014 ni ìjọba Turkmenistan ti ń rán àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lọ ṣiṣẹ́ àṣekára lérò àtibá wọn wí. Ara ìyà tí wọ́n fi ń jẹ irú àwọn yìí ni pé láàárín ọdún kan sí méjì, wọ́n gbọ́dọ̀ máa san ìdá márùn-ún owó oṣù wọn fún Ìjọba. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Ẹlẹ́rìí méjì ni wọ́n ti rán lọ sẹ́nu iṣẹ́ àṣekára lérò àtibá wọn wí.

  • Láwọn ìgbà míì, ṣe ni àwọn aláṣẹ máa ń fúngun mọ́ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun gidigidi kí wọ́n lè fipá mú wọn ṣe ohun tó ta ko nǹkan tí wọ́n gbà gbọ́.

Artur Yangibayev

Bí àpẹẹrẹ, ní June 16, 2016, agbófinró ìlú àtàwọn aṣojú Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwọn Ológun lọ sílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Artur Yangibayev. Ó ti kọ̀wé sí ìjọba pé kí wọ́n jẹ́ kóun ṣiṣẹ́ àṣesìnlú, àmọ́ wọ́n mú un lọ sí ọ́fíìsì agbẹjọ́rò, wọ́n sì fúngun mọ́ ọn gidigidi níbẹ̀ débi pé wọ́n fipá mú un kọ lẹ́tà pé òun fagi lé ìwé tóun kọ́kọ́ kọ. Nígbà tó yá, Ọ̀gbẹ́ni Yangibayev kọ̀wé láti fẹjọ́ sùn lórí bí àwọn aláṣẹ ṣe fúngun mọ́ ọn yìí, lẹ́yìn tí wọ́n sì tì í mọ́lé fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, wọ́n dá a sílẹ̀, àmọ́ wọ́n sọ pé àwọn á ṣì máa ṣọ́ ọ fún ọdún méjì. *

Àwọn Ọ̀rọ̀ Míì Tó Jẹ Mọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn tí Kò Tíì Lójú

Yàtọ̀ sí pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan ń fìyà tí kò tọ́ jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, wọn ò jẹ́ káwọn aráàlú ráyè jọ́sìn Ọlọ́run, wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Fífìyà Jẹni lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè gbé ìròyìn kan jáde ní January 2017, wọ́n rọ ìjọba Turkmenistan pé kí wọ́n “rí i pé wọ́n tètè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèwádìí tó jinlẹ̀ láìṣègbè . . . lórí ọ̀rọ̀ Bahram Hemdemov, Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n tì mọ́lé ní May 2015, tá a gbọ́ pé wọ́n ń fìyà jẹ [àti] lórí ọ̀rọ̀ Mansur Masharipov, Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mú ní July 2014, tí wọ́n lù nílùkulù, tí wọ́n sì fipá tì í mọ́lé níléeṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó ti sọ oògùn olóró di bárakú.” Wọ́n ti tú Ọ̀gbẹ́ni Masharipov sílẹ̀ lẹ́yìn tó lo ọdún kan lẹ́wọ̀n. Wọ́n sọ pé Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov jẹ̀bi torí pé ó ń ṣe ìjọsìn tí kò bófin mu, wọ́n sì fi Ọ̀gbẹ́ni Masharipov sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn irọ́ tí wọ́n lọ́ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ torí pé ó ń sin Ọlọ́run, àmọ́ àwọn méjèèjì ò mọwọ́ mẹsẹ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Turkmenistan ń retí pé láìpẹ́, ìjọba máa wá nǹkan ṣe sáwọn ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n á sì gbé òmìnira ẹ̀sìn àti ẹ̀rí ọkàn lárugẹ. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa fi hàn pé wọ́n gbà pé àwọn ọkùnrin yẹn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ káwọn ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n á sì fi hàn pé àwọn ń tiraka lóòótọ́ láti ṣàtúnṣe lórí bí wọ́n ti ṣe fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àwọn èèyàn dù wọ́n.

^ ìpínrọ̀ 2 Òfin ìjọba àpapọ̀ kárí ayé fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé òun ò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló sì ṣòfin tó fọwọ́ sí i. Àmọ́, ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan, Azerbaijan, Eritrea, Singapore, South Korea àti Tọ́kì ò gbà pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, kódà, wọn ò yéé pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun lẹ́jọ́.

^ ìpínrọ̀ 18 Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé dípò tí wọ́n á fi rán an lẹ́wọ̀n, wọn ò ní jẹ́ kó lómìnira, ṣe ni wọ́n á máa ṣọ́ ọ. Àwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ Ọ̀gbẹ́ni Yangibayev lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, àmọ́ wọn ò tíì fi sẹ́wọ̀n.