Ní March 23, 2016, àwọn ọlọ́pàá fẹ́ ya wọ ilé àdáni kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye wọn jẹ́ ogún (20) kóra jọ sí nílùú Turkmenabad, lórílẹ̀-èdè Turkmenistan láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún, àmọ́ wọn ò ráyè wọlé. Síbẹ̀, wọn ò kúrò níta. Ìkankan nínú àwọn tó wà nínú ilé ò jẹ́ jáde síta, wọ́n yáa sun ibẹ̀ mọ́jú.

Lọ́jọ́ kejì, àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin fipá gba ibi ọ̀dẹ̀dẹ̀ ilé náà wọlé. Wọ́n lù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Ọwọ́ tí wọ́n gbé wá le gan-an débi pé wọ́n pa obìnrin olóyún kan lára, ó sì di dandan kó lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn. Gbogbo àwọn tó wà nínú ilé náà ni wọ́n kó lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, wọ́n sì lu ọkùnrin méjì lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n kó wọn débẹ̀. Ní March 25, wọ́n tú gbogbo àwọn tí wọ́n tì mọ́lé sílẹ̀, àfi ọkùnrin kan tó lo ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún látìmọ́lé. Ní April 19, ìjọba bu owó ìtanràn lé méje nínú àwọn Ẹlẹ́rìí náà láìjẹ́ kí wọ́n fojú ba ilé ẹjọ́, wọ́n ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan san iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000) owo náírà.