Nínú ìpinnu mẹ́rin kan tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n sọ pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan fìyà tí kò tọ́ jẹ àwọn ọkùnrin tó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. * Ó tún sọ pé wọ́n rú àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights (ICCPR) tó dá lórí ẹ̀tọ́ tí àwọn aráàlú àtàwọn olóṣèlú ní. Àjọ yìí wá pinnu pé kí orílẹ̀-èdè Turkmenistan wá nǹkan ṣe sí bí wọ́n ṣe rú òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn jákèjádò ayé.

Ọ̀kan La Ń Yanjú, Òmíràn Tún Rú Jáde

Ní March 2015 àjọ yìí tún ẹjọ́ ọ̀gbẹ́ni Zafar Abdullayev tó jẹ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Turkmenistan gbé yẹ̀ wò. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n fòfin ọba mú ọ̀gbẹ́ni yìí nítorí ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Nígbà tí wọ́n pe ọ̀gbẹ́ni Abdullayev sílé ẹjọ́ ní April 2009, ó sọ nílé ẹjọ́ náà nílùú Dashoguz pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí òun ṣe ló jẹ́ kí òun pinnu pé òun ò ní fọwọ́ kan ohun ìjà ogun kankan, òun ò ní kọ́ṣẹ́ ogun tàbí kóun kọ́wọ́ ti àwọn ológun. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé dípò kí òun ṣe iṣẹ́ ológun, òun ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ míì láti fi sin ìlú. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo nǹkan tó sọ yìí ṣe ni wọ́n tún fi í sẹ́wọ̀n àfidípò * ọdún méjì fún ẹ̀sùn pé ó “kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.”

Lẹ́yìn nǹkan bíi oṣù mọ́kànlá tó jáde lẹ́wọ̀n, wọ́n tún pe ọ̀gbẹ́ni Abdullayev sílé ẹjọ́ yìí kan náà pé ó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun. Síbẹ̀ ọ̀gbẹ́ni yìí ò yí ìpinnu rẹ̀ pa dà. Ilé ẹjọ́ sì tún dá ẹ̀wọ̀n ọdún méjì míì fún-un.

Ìgbìmọ̀ wá sọ pé bí wọ́n ṣe fìyà tí kò tọ́ jẹ ọ̀gbẹ́ni Abdullayev, mú kí wọ́n rú òfin tó sọ pé “wọn ò gbọdọ̀ fìyà jẹ ẹnì kan lẹ́ẹ̀kejì fún ẹ̀sùn kan náà tó ti jìyà rẹ̀ tẹ́lẹ̀.” (Wo ICCPR Àpilẹ̀kọ 14, ìpínrọ̀ 7.) Níparí ọ̀rọ̀ wọn, Ìgbìmọ̀ náà sọ pé bí ilé ẹjọ́ ṣe dá arákùnrin yìí lẹ́bi lẹ́ẹ̀mejì ta ko ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó dá lórí “òmìnira láti ronú, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni bá fẹ́ àti ẹ̀sìn tó wuni.”—Wo ICCPR Àpilẹ̀kọ 18, ìpínrọ̀ 1.

“Ẹ̀tọ́ tí ẹnì kan ní láti kọ iṣẹ́ ológun wà lára ẹ̀tọ́ tó dá lórí òmìnira láti ronú, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni bá fẹ́ àti ẹ̀sìn tó wuni. Ẹ̀tọ́ yìí gba ẹnikẹ́ni láyè láti kọ iṣẹ́ ológun tí kò bá bá ẹ̀sìn rẹ̀ tàbí ohun tó gbà gbọ́ mu.”—Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè

Ìgbésí Ayé Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Ọ̀gbẹ́ni Abdullayev dé ọgbà ẹ̀wọ̀n Seydi LBK-12 ni wọ́n ti lọ fí òun nìkan síbì kan fún ọjọ́ mẹ́wàá gbáko. Nígbà tó débẹ̀, ṣe làwọn wọ́dà lù ú ní àlùbami, wọ́n sì tún fi ìyà tí kò tọ́ jẹ ẹ́ lóríṣiríṣi.

Láàárín ọdún 2010 àti 2011, wọn tún fi àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta míì sẹ́wọ̀n torí pé wọn ò wọṣẹ́ ológun, àwọn ni Ahmet Hudaybergenov, Mahmud Hudaybergenov, àti Sunnet Japparow. Wọ́n tún lu àwọn náà ní àlùbami, wọ́n sì tún fi ìyà tí kò tọ́ jẹ wọ́n.

Zafar Abdullayev

Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí sọ nípa bí nǹkan ṣe rí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n jọra. Nǹkan bí ogójì (40) ẹlẹ́wọ̀n ni wọ́n fún mọ́ yàrá ọgbà ẹ̀wọ̀n kan. Yàrá ọ̀hún dọ̀tí gan-an, kò sí ibi tí wọ́n lè jókòó sí, ilẹ̀ ńlẹ̀ lásán ni wọ́n ń jókòó sí. Tó bá sì tún dalẹ́, aṣọ ìbora tó ti dọ̀tí tí kò sì tún ní kárí ni wọ́n á tún kó fáwọn ẹlẹ́wọ̀n náà.

Ní October 2015, Ìgbìmọ̀ náà yẹ ẹjọ́ Ọ̀gbẹ́ni Hudaybergenov, Hudaybergenov, àti Japparow wò. Ìpinnu tí ìgbìmọ̀ náà ṣe fara jọ ohun tí wọ́n sọ nínú ọ̀ràn Ọ̀gbẹ́ni Abdullayev. Wọ́n sọ pé ìyà táwọn aláṣẹ fi jẹ àwọn ọkùnrin yìí mú kí wọ́n rú òfin tó sọ pé “wọn ò gbọ́dọ̀ dá ẹnikẹ́ni lóró tàbí hàn án léèmọ̀, hùwà ìkà sí i tàbí ṣe é ṣúkaṣùka.” (Wo ICCPR Àpilẹ̀kọ 7.) Ìgbìmọ̀ yìí tún sọ pé bí wọn ò ṣe fún wọn ní ilé tó bójú mu yìí rú òfin ẹ̀tọ́ tí ẹlẹ́wọ̀n ní láti “gba ìtọ́jú gidi lọ́dọ̀ ìjọba kí wọ́n sì fi ọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n bíi tàwọn èèyàn tó kù tí kò sí lẹ́wọ̀n.”—Wo ICCPR Àpilẹ̀kọ 10.

Ó Yẹ Kí Wọ́n Wá Nǹkan Ṣe sí Bí Wọ́n Ṣe Tẹ Òfin Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lójú

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbà pé ìjọba òfin orílẹ̀-èdè Turkmenistan ń fipá mú àwọn ọmọkùnrin ilẹ̀ náà wọṣẹ́ ológun. Àmọ́, Ìgbìmọ̀ náà sọ pé àdéhùn ICCPR ti mú kó ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti sọ pé òun kò wọṣẹ́ ológún nítorí ohun tí òun gbà gbọ́. Wọ́n sọ pé bí wọ́n ṣe ń fìyà tí kò tọ́ jẹ àwọn èèyàn yìí, tí wọ́n sì tún ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n kò bá ẹ̀tọ́ tó dá lórí “òmìnira láti ronú, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni bá fẹ́ àti ẹ̀sìn tó wuni” mu.

Ohun tí Ìgbìmọ̀ yìí pinnu ni pé dandan ni kí ìjọba Turkmenistan “ṣòfin pé èèyàn lè yàn láti má wọṣẹ́ ológun,” kí wọ́n ṣèwádìí nípa ọ̀rọ̀ tó bá kan “ìwà òǹrorò, ìwà ìkà tàbí fífi ìtọ́jú tó bá yẹ dunni,” kí wọ́n sì fìyà tó tọ́ jẹ ẹnikẹ́ni tó bá hùwà yìí. Ìgbìmọ̀ náà sì tún sọ pé kí ìjọba ṣàtúnṣe tó bá yẹ fún àwọn tí wọ́n ti fi ìyà àìtọ́ jẹ, lára ohun tí wọ́n máa ṣe ni pé kí wọ́n san owó ìtanràn tó bá yẹ fún wọn, kí wọ́n sì pa àkọsílẹ̀ èyíkéyìí tó bá sọ pé wọ́n rú òfin ìjọba bí wọn ò ṣe wọṣẹ́ ológun rẹ́.

Ó Yẹ Kí Ìtẹ̀síwájú Ṣì Wà

Ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan ti tẹ̀ síwájú nínú bí wọ́n ṣe ń yanjú ọ̀ràn àwọn tí wọn ò ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà láyè. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí wọn ò wọṣẹ́ ológun ni wọ́n ti dá sílẹ̀. March 2015 ni wọ́n dá ẹni tó gbẹ̀yìn sẹ́wọ̀n lára wọn sílẹ̀.

Àmọ́, àwọn míì ṣì wà lẹ́wọ̀n torí àwọn nǹkan míì tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gbà wọ́n láti ṣe. Bahram Hemdemov tó ti ní ìdílé, tó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì wà lẹ́wọ̀n. Àwọn ọlọ́pàá mú un nígbà tí ìjọsìn ń lọ lọ́wọ́ ní ilé rẹ̀ ní March 14, 2015. Ilé ẹjọ́ kan dá ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin fún ún torí pé ó ń ṣe ìjọsìn nílé rẹ̀. Ní báyìí, ọ̀gbẹ́ni Hemdemov ń fara da ìjìyà àti ipò tí kò rọgbọ lágọ̀ọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà nílùú Seydi.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn tó ń gbé Turkmenistan ń wọ̀nà fún ìgbà tí ìjọba Turkmenistan máa ṣe ohun tí ìjọba ìparapọ̀ ní kí wọ́n ṣe nípa bíbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, títí kan ẹ̀tọ́ tó dá lórí òmìnira láti ronú, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni bá fẹ́ àti ẹ̀sìn tó wuni.

^ ìpínrọ̀ 2 Wo UN Human Rights Committee Communications: No. 2218/2012, Zafar Abdullayev v. Turkmenistan, 25 March 2015 (CCPR/C/113/D/2218/2012); No. 2221/2012, Mahmud Hudaybergenov v. Turkmenistan, 29 October 2015 (CCPR/C/115/D/2221/2012); No. 2222/2012, Ahmet Hudaybergenov v. Turkmenistan, 29 October 2015 (CCPR/C/115/D/2222/2012); No. 2223/2012, Sunnet Japparow v. Turkmenistan, 29 October 2015 (CCPR/C/115/D/2223/2012).

^ ìpínrọ̀ 4 Ẹ̀wọ̀n àfidípò túmọ̀ sí pé kí wọ́n ṣòfin tó máa dín òmìnira ẹnì kan kù kàkà kí wọ́n fi í sẹ́wọ̀n. Ní ti ọ̀ràn ọ̀gbẹ́ni Abdullayev, ó gbà kí àwọn ọlọ́pàá máa ṣọ́ òun ní gbogbo ìgbà àmọ́ kò lọ sẹ́wọ̀n.