Ní May 12, 2017, ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan dá Mansur Masharipov sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Inú ẹ̀ dùn láti pa dà sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀, lẹ́yìn tó ti lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan lẹ́wọ̀n.

Nígbà kan ọ̀gbẹ́ni Masharipov kọ̀ láti wọ iṣẹ́ ológun torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò gbà á láyè. Ní May 2004, ilé ẹjọ́ tó wà ní Dashoguz rán an lọ sẹ́wọ̀n fún ọdún kan àtààbọ̀ ní àgọ́ iṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Seydi. Àgọ́ yìí kún fún ìwà ìkà, ebi àti àìsàn. Ó ṣàìsàn gan-an nígbà yẹn, àmọ́ ìjọba pa dà dá a sílẹ̀ ní May 2005. Ní July 2014, àwọn ọlọ́pàá lọ sílé rẹ̀, wọ́n tú gbogbo inú ilé rẹ̀, wọ́n sì kó àwọn ìtẹ̀jáde níbẹ̀. Nígbà tó wà ní àgọ́ àwọn ọlọ́pàá, wọ́n lù ú lálùbami, wọ́n tún halẹ̀ mọ́ ọn, lẹ́yìn náà wọ́n mú un lọ sí ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó ń lo oògùn nílòkulò láti lọ gún un ni àwọn abẹ́rẹ́ burúkú kan. Àwọn abẹ́rẹ́ yẹn dá àìsàn síi lára, ó tún sọ ọ́ di ẹni tó rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀. Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni Masharipov rí i pé wọ́n fẹ́ pa òun, ó sá lọ síbì kan, ibi tó sá lọ yẹn ló wà títí tí wọ́n fi tún rí i mú ní June 30, 2016.

Inú Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn gan-an bí wọ́n ṣe dá ọ̀gbẹ́ni Masharipov sílẹ̀. Síbẹ̀, ọkàn wa bà jẹ́ bí ìjọba Turkmenistan ṣe ń ṣàtakò líle sí wa láti fi òmìnira ẹ̀sìn dù wá. Àwa Ẹlẹ́rìí tún ń sapá gidigidi kí wọ́n lè dá Bahram Hemdemov sílẹ̀. Ọdún kẹta rẹ̀ ló ń lò lọ yìí ní àgọ́ iṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Seydi torí pé òun àti àwọn Ẹlẹ́rìí kan ń jọ́sìn nínú ilé rẹ̀.