Láti oṣù June sí August ọdún 2018, àwọn aláṣẹ lórílẹ̀-èdè Turkmenistan ju Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Wọn rán Ihlosbek Rozmetov, Veniamin Genjiyev, Maksat Jumadurdiyev, Isa Sayayev, Ruslan Artykmuradov, Sokhbet Agamyradov pẹ̀lú Serdar Atayev lọ sẹ́wọ̀n ọdún kan, wọ́n sì rán Mekan Annayev lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjì.

Kò tíì sí ẹnì kankan tí wọ́n rán lọ́ sẹ́wọ̀n tórí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun lẹ́yìn àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́jọ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí lórílẹ̀ èdè Turkmenistan. Ní oṣù January 2018, àwọn aláṣẹ ti dẹ́bi fún àwọn méjì kan torí pé wọ́n sọ pé àwọn ò lè ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì ju àwọn méjèèjì sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan, * àwọn ni Arslan Begenjov àti Kerven Kakabayev. Àwọn méjì yìí ni wọ́n kọ́kọ́ fi sẹ́wọ̀n lórí ọ̀rọ̀ yìí láti oṣù February ọdún 2015. Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Seydi (LBK-12) tí Bahram Hemdemov wà láti ohun tó lé ní ọdún mẹ́ta báyìí ni wọ́n fi àwọn ọkùnrin méjì yìí àti mẹ́rin lára àwọn mẹ́jọ tó kù tí wọ́n dá lẹ́bi sí.

Wọ́n Fi Bahram Hemdemov Sẹ́wọ̀n Láìtọ́

Ní March 14, 2015, àwọn ọlọ́pàá ìlú Turkmenabad ya wọ ilé Ọ̀gbẹ́ni Bahram Hemdemov, níbi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀. Wọ́n mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlógójì (38), wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń jọ́sìn lọ́nà tó ta ko òfin. Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ṣúkaṣùka, wọ́n bu owó ìtanràn lé ọgbọ̀n (30) nínú wọn, wọ́n sì rán àwọn mẹ́jọ lọ sẹ́wọ̀n ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15). Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Lebap wá rán Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin. Nǹkan ò fara rọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Seydi rárá, ìyẹn sì ti ṣàkóbá fún ìlera Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov gan-an. Àìmọye ìgbà láàárín ọdún ní ààrẹ máa ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń gbójú fo Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní yìí bá yọjú.

Ọ̀rọ̀ Lórí Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn, Ẹ̀sìn àti Ìgbàgbọ́ Kò Tíì Yanjú

Lọ́dún 2015 àti 2016, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè (ìyẹn Ìgbìmọ̀ CCPR) ṣe ìpinnu mẹ́wàá tó dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan láre. Àwọn ọkùnrin yìí ti kọ̀wé sí ìgbìmọ̀ yìí torí ìjọba rán wọn lọ sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n gidigidi lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí ti fi ẹ̀sùn méje míì kan ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan lọ́dọ̀ àjọ CCPR.

Ní April 2012, ìgbìmọ̀ CCPR rọ ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan pé “kí wọ́n rí i pé àwọn òfin àti ìlànà tí wọ́n ṣe lórí ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀sìn tó fẹ́ forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin kò ta ko òmìnira àti ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́, kí wọ́n sì sọ ọ́ fáwọn míì, bó ṣe wà nínú [àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights].” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ látọdún 2008, àmọ́ ìjọba ò tíì fọwọ́ sí i.

À Ń Retí Pé Nǹkan Máa Dáa Sí I

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn pé nígbà kan, ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ kí wọ́n lè ṣàtúnṣe ìwà ìrẹ́jẹ tó ń wáyé. * Àmọ́ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí ń fi hàn pé ìjọba ilẹ̀ yìí tún ti ń kọ etí ikún sí ọ̀rọ̀ tí oríṣiríṣi àjọ kárí ayé sọ pé kó má fi ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní dù wọ́n tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń retí ohun tí ìjọba máa ṣe lórí àwọn ohun tí ìgbìmọ̀ CCPR sọ nínú ẹjọ́ tí wọ́n dá lórí ọ̀rọ̀ àwọn ohun tó jẹ mọ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, pàápàá lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀rí ọkàn, ẹ̀sìn àti òmìnira láti gba ohun tó wuni gbọ́.

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

 1. September 7, 2018

  Iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lẹ́wọ̀n di mọ́kànlá.

 2. August 28, 2018

  Wọ́n dá Serdar Atayev lẹ́bi pé kò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, wọ́n sì rán an lẹ́wọ̀n ọdún kan.

 3. August 27, 2018

  Wọ́n dá Sokhbet Agamyradov lẹ́bi pé kò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, wọ́n sì rán an lẹ́wọ̀n ọdún kan.

 4. August 13, 2018

  Wọ́n dá Ruslan Artykmuradov lẹ́bi pé kò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, wọ́n sì rán an lẹ́wọ̀n ọdún kan.

 5. August 9, 2018

  Wọ́n dá Isa Sayayev lẹ́bi pé kò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, wọ́n sì rán an lẹ́wọ̀n ọdún kan.

 6. July 17, 2018

  Wọ́n dá Veniamin Genjiyev àti Maksat Jumadurdiyev lẹ́bi pé wọn ò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn, wọ́n sì rán wọn lẹ́wọ̀n ọdún kan.

 7. July 11, 2018

  Wọ́n dá Ihlosbek Rozmetov lẹ́bi pé kò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, wọ́n sì rán an lẹ́wọ̀n ọdún kan.

 8. June 26, 2018

  Wọ́n dá Mekan Annayev lẹ́bi pé kò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, wọ́n sì rán an lẹ́wọ̀n ọdún méjì.

 9. January 29, 2018

  Ilé ẹjọ́ dá Kerven Kakabayev lẹ́bi nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò gbà á láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan.

 10. January 17, 2018

  Ilé ẹjọ́ dá Arslan Begenjov lẹ́bi nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò gbà á láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan.

 11. May 12, 2017

  Àwọn aláṣẹ ní Turkmenistan dá Mansur Masharipov sílẹ̀. Láti June 30, 2016 ni wọ́n ti mú un, tí wọ́n ti tì í mọ́lé.

 12. August 18, 2016

  Ilé ẹjọ́ sọ pé Mansur Masharipov jẹ̀bi ẹ̀sùn irọ́ tí wọ́n lọ́ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún kan.

 13. July 2016

  Ìgbìmọ̀ CCPR dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan láre nínú ẹjọ́ mẹ́fà tí wọ́n dá, lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ti dá wọn lẹ́bi torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

 14. December 14, 2015

  Ìgbìmọ̀ CCPR dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ta láre, lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ti dá wọn lẹ́bi torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Wọ́n tún dá wa láre nínú ẹjọ́ míì tí wọ́n dá ṣáájú èyí ní May 19, 2015.

 15. May 19, 2015

  Ilé ẹjọ́ dá Bahram Hemdemov lẹ́bi torí pé ó ń jọ́sìn Ọlọ́run, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin. Ṣáájú ìgbà yẹn, wọ́n mú un, wọ́n sì tì í mọ́lé fún oṣù méjì kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀.

 16. February/⁠March 2015

  Wọ́n dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sílẹ̀. Ìgbìmọ̀ CCPR dá Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan láre, lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ti dá a lẹ́bi torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.

 17. November 18, 2014

  Wọ́n fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

 18. October 22, 2014

  Ààrẹ orílẹ̀-èdè Turkmenistan dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ sílẹ̀ lẹ́wọ̀n.

 19. September 30, 2014

  Wọ́n rán àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́sàn-án lọ sẹ́wọ̀n, àwọn méje torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì lọ́ ẹ̀sùn mọ́ àwọn méjì tó kù lẹ́sẹ̀ torí pé wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run, làwọn náà bá dèrò ẹ̀wọ̀n.

 20. September 2, 2014

  Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Turkmenistan dá Bibi Rahmanova sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin tí wọ́n rán an lọ, àmọ́ wọ́n á ṣì máa ṣọ́ ọ títí ọdún mẹ́rin yẹn á fi pé.

 21. August 18, 2014

  Ilé ẹjọ́ dá Bibi Rahmanova lẹ́bi ẹ̀sùn èké tí wọ́n lọ́ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin.

 22. July 25, 2014

  Wọ́n rán àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méje lọ sẹ́wọ̀n, àwọn márùn-ún torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì lọ́ ẹ̀sùn mọ́ àwọn méjì tó kù lẹ́sẹ̀ torí pé wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run, làwọn náà bá dèrò ẹ̀wọ̀n.

 23. April 6, 2014

  Wọ́n ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n mọ́lé, kò sì sí ẹ̀rí pé mẹ́tàlá [13] nínú wọn ṣe ohunkóhun tó ta ko òfin. Wọ́n wá bu owó ìtanràn lé àwọn mẹ́tàlá náà.

 24. November 2013

  Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́sàn-án ṣì wà lẹ́wọ̀n, àwọn mẹ́jọ torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì lọ́ ẹ̀sùn mọ́ ẹnì kan tó kù lẹ́sẹ̀ torí pé ó ń jọ́sìn Ọlọ́run, lòun náà bá dèrò ẹ̀wọ̀n.

 25. August 29, 2013

  Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ta kọ̀wé sí ìgbìmọ̀ CCPR torí pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan ò fọwọ́ sí i pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ àtikọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é.

 26. May 1, 2013

  Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kọ̀wé sí ìgbìmọ̀ CCPR torí pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan ò fọwọ́ sí i pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ àtikọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é.

 27. January 24, 2013

  Àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n [30] ya wọ ilé Navruz Nasyrlayev ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ CCPR bá ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan sọ̀rọ̀ lórí àwọn tó fẹjọ́ sùn. Léraléra ni àwọn ọlọ́pàá lu ìdílé yìí àtàwọn àlejò tó wà nínú ilé wọn.

 28. September 7, 2012

  Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́wàá kọ̀wé sí ìgbìmọ̀ CCPR torí pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan ò fọwọ́ sí i pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ àtikọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é. Navruz Nasyrlayev ni ọ̀rọ̀ yìí ká lára jù.

 29. August 21, 2008

  Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀wé síjọba pé àwọn fẹ́ forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Turkmenistan.

^ ìpínrọ̀ 3 Òfin tí àwọn aláṣẹ ń lò láti fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ni Apá 219, abala kìíní nínú Òfin Ìwà Ọ̀daràn tó sọ pé: “Iṣẹ́ àṣekára ọdún méjì tàbí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì ni ìyà tá a máa fi jẹ ẹnikẹ́ni tó bá kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun láìní ìdí kankan lábẹ́ òfin.”