Àtọdún 1931 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà ní orílẹ̀-èdè Tọ́kì. Wọ́n gbógun tì wọ́n lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn títí di nǹkan bí ọdún 1985 sí 1989. Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í dẹwọ́, wọ́n sì gbà káwọn Ẹlẹ́rìí máa jọ́sìn àmọ́ wọn ò gbà kí wọ́n forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Ní July 2007, nǹkan yí pa dà. Àwọn ilé ẹjọ́ ní orílẹ̀-èdè Tọ́kì dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá lè pàdé pọ̀ báyìí láti jọ́sìn, wọ́n sì lómìnira láti máa ṣe ẹ̀sìn wọn dé ìwọ̀n àyè kan.

Àmọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Tọ́kì ò gbà pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kó ṣe é. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n ti ń pe àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun léraléra pé kí wọ́n wá wọṣẹ́ ológun dandan, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pè wọ́n lẹ́jọ́, wọ́n ń bu owó ìtanràn gọbọi lé wọn, wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Látọdún 2011, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn ilé ẹjọ́ ECHR) ti dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre nínú ẹjọ́ mẹ́ta tí wọ́n dá, nígbà tó sì di ọdún 2012, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣe ìpinnu tó gbe àwọn Ẹlẹ́rìí lórí ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Tọ́kì ṣì ń pe àwọn ọ̀dọ́kùnrin àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lẹ́jọ́.

Lọ́dún 2003, ìjọba orílẹ̀-èdè Tọ́kì ṣàtúnṣe sí òfin tí wọ́n ṣe lórí ọ̀rọ̀ ilé kíkọ́, kí àwọn ẹ̀sìn kéékèèké tí kì í ṣe Mùsùlùmí lè kọ́ ibi tí wọ́n á ti máa jọ́sìn. Àmọ́ àwọn aláṣẹ ìlú kan àtàwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò kò tẹ̀ lé e, wọn kì í fọwọ́ sí i pé “ibi ìjọsìn” ni Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹjọ́ méjì ló ṣì wà nílé ẹjọ́ ECHR lórí ọ̀rọ̀ yìí.