Ní May 24, 2016, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn ilé ẹjọ́ ECHR) fún àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké tó wà lórílẹ̀-èdè Turkey lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Ìdájọ́ tí wọ́n ṣe yìí ló jẹ́ kí wọ́n lè rí nǹkan ṣe sí bí ìjọba orílẹ̀-èdè náà ṣe ń fi òfin tó kan ọ̀rọ̀ ilé kíkọ́ de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọn ò sì fọwọ́ sí i pé “ibi ìjọsìn” ni àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí.

Ilé ẹjọ́ ECHR rí i pé òfin tí ìjọba orílẹ̀-èdè Turkey ṣe lórí ọ̀rọ̀ ilé kíkọ́ fọwọ́ sí i pé kí àwọn ilé ńlá jẹ́ “ibi ìjọsìn,” àmọ́ òfin yìí ò fàyè gba àwọn ilé tó mọ níwọ̀n tí àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké lè máa lò fún ìjọsìn. Ìyẹn ti wá mú kí ìjọba máa ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kò, wọn ò sì jẹ́ kí wọ́n lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ṣe yìí ta ko Àpilẹ̀kọ 9 nínú àdéhùn European Convention on Human Rights. * Ilé ẹjọ́ náà sọ pé ṣe ni àwọn aláṣẹ ń fi òfin ilé kíkọ́ tí wọ́n ṣe yìí “fúngun mọ́ àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké, irú bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ń béèrè ohun tó kọjá agbára wọn [kí wọ́n tó lè ṣèjọsìn].”

Òfin Ilé Kíkọ́ Ò Fàyè Gba Àwọn Ẹlẹ́sìn Kéékèèké

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Turkey, ó sì ti pẹ́ tí wọ́n ti ń gbìyànjú pé kí àwọn aláṣẹ fọwọ́ sí i pé “ibi ìjọsìn” ni àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, lábẹ́ òfin ilé kíkọ́ tí ìjọba ṣe. Àmọ́ léraléra ni àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè náà kọ̀ láti fọwọ́ sí i pé “ibi ìjọsìn” ni Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn aláṣẹ tí wá ń halẹ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà léraléra pé gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn márùndínlọ́gbọ̀n (25) tó wà lórílẹ̀-èdè Turkey làwọn máa tì pa, tí wọ́n á sì gbẹ́sẹ̀ lé e torí pé òfin ilé kíkọ́ ò ka àwọn ilé náà sí “ibi ìjọsìn.” Láti August 2003, àìmọye ìgbà ni àwọn aláṣẹ ti ti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Mersin àti Akçay pa. Lágbègbè Karşıyaka nílùú İzmir, àwọn aláṣẹ kọ̀ láti fọwọ́ sí i pé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níbẹ̀ bí ibi ìjọsìn. Títì tí àwọn aláṣẹ ti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Mersin àti Akçay pa ló bí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR dá ní May 24.

Ṣáájú ọdún 2003, àwọn tó bá fẹ́ kọ́ mọ́ṣáláṣí ni òfin ilé kíkọ́ tí ìjọba orílẹ̀-èdè Turkey ṣe nípa ọ̀rọ̀ ibi ìjọsìn kàn. Lásìkò yẹn, àwọn aláṣẹ ìlú ò dí àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ láti pà dé nílé ara wọn. Àmọ́ lọ́dún 2003, ìjọba orílẹ̀-èdè Turkey ṣàtúnṣe sí Òfin Ilé Kíkọ́ No. 3194, kó lè bá ìlànà tí ìjọba ilẹ̀ Yúróòpù fi lọ́lẹ̀ mu lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tanú àti òmìnira ẹ̀sìn. Ara àwọn àtúnṣe tí wọ́n ṣe sí òfin náà ni pé wọ́n yọ ọ̀rọ̀ náà, “mọ́ṣáláṣí” kúrò, wọ́n sì fi “ibi ìjọsìn” rọ́pò rẹ̀. Wọ́n tún sọ níbẹ̀ pé kí àwọn aláṣẹ ìlú máa rí i pé ilẹ̀ wà táwọn ẹlẹ́sìn á fi kọ́ ibi ìjọsìn.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn àtúnṣe tí wọ́n ṣe sí òfin yìí yẹ kó gba àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké láyè láti ní ibi ìjọsìn tàbí kí wọ́n kọ́ ọ. Àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan míì ni wọ́n ti lọ́ mọ́ òfin yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kọ ọ́ sínú òfin náà bí ilé tó bá máa jẹ́ ibi ìjọsìn ṣe gbọ́dọ̀ fẹ̀ tó, pé ó gbọ́dọ̀ gba ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn olùjọ́sìn àti pé kí wọ́n kọ́ ọ bí ilé táwọn Mùsùlùmí máa ń lò fún ìjọsìn.

Bí Ìjọba Ṣe Ń Rin Kinkin Mọ́ Òfin Ò Jẹ́ Káwọn Ẹlẹ́sìn Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Ní “Ibi Ìjọsìn”

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn aláṣẹ ìlú ò fún àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké ní ilẹ̀ tí wọ́n lè fi kọ́ ibi ìjọsìn tí ò tóbi. Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá sì kọ̀wé sí wọn pé kí wọ́n bá wọn wá nǹkan ṣe sí i, ṣe ni wọ́n máa ń wọ́gi lé e. Bẹ́ẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí náà ń kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí àwọn ilé ẹjọ́ gíga àtàwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ ibi pẹlẹbẹ lọ̀bẹ ń fi lélẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń rin kinkin mọ́ òfin, wọ́n sì kọ̀ láti fọwọ́ sí i pé “ibi ìjọsìn” ni Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn aláṣẹ ìlú Mersin àti Akçay rin kinkin mọ́ òfin tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yìí, wọ́n sì ti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níbẹ̀ pa torí wọn ò sí lára ibi tí wọ́n fọwọ́ sí pé ó jẹ́ “ibi ìjọsìn.” Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kí wọ́n fún àwọn níbòmíì táwọn ti lè máa jọ́sìn, àwọn aláṣẹ sọ fún wọn pé kò síbi tí òfin fọwọ́ sí tí wọ́n ti lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

Jákèjádò orílẹ̀-èdè Turkey ni nǹkan ti há báyìí. Ìjọba ò fọwọ́ sí ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké míì ń lò fún ìjọsìn. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ìgbà mẹ́rìndínláàádọ́ta (46) làwọn aláṣẹ ní àwọn àgbègbè mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) lórílẹ̀-èdè Turkey ti kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ibi tí òfin fọwọ́ sí láti máa jọ́sìn. Bákan náà, àwọn ilé ìjọsìn tí ìjọba fọwọ́ sí kì í sanwó orí, owó iná àti owó omi, àmọ́ àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń san àwọn owó yìí torí pé òfin ò fọwọ́ sí ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Kọ̀wé Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ ECHR Kí Wọ́n Lè Gbà Wọ́n Sílẹ̀

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ nígbà tí kò lójú, wọ́n kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí ilé ẹjọ́ ECHR. Látìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń sapá kí ìjọba lè gba wọ́n láyè láti máa lo àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn fún ìjọsìn, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin orílẹ̀-èdè Turkey, ìyẹn ilé ẹjọ́ tó ga jù nílẹ̀ náà, kò fọwọ́ sí i . Ilé ẹjọ́ kan tiẹ̀ dá àwọn Ẹlẹ́rìí láre lórí ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin wọ́gi lé e.

Ìyẹn wá mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀wé sí ilé ẹjọ́ ECHR lọ́dún 2010 àti 2012, wọ́n ní kí Ilé Ẹjọ́ náà wò ó bóyá ìjọba orílẹ̀-èdè Turkey ti ṣe ohun tó ta ko àdéhùn European Convention on Human Rights. Ohun tí ilé ẹjọ́ ECHR sì ti sọ tẹ́lẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ tó jọ èyí náà ni wọ́n gùn lé, wọ́n sọ pé ó yẹ kí òfin ilẹ̀ fàyè gba àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké láti ní ibi ìjọsìn.

Ilé ẹjọ́ ECHR kíyè sí i pé “agbára káká ni àwọn ẹlẹ́sìn kékeré bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà á fi lè ṣe ohun tí òfin tó bí ẹjọ́ yìí ní kí wọ́n ṣe kí wọ́n tó lè ní ibi tó yẹ tí wọ́n á ti máa jọ́sìn.” Ilé ẹjọ́ náà wá sọ pé: “Àwọn ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè Turkey ò ro tàwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké mọ́ tiwọn. . . . Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò pọ̀, kì í ṣe ilé ńlá kan ni wọ́n nílò. Tí wọ́n bá ti ní ilé kan tó mọ níwọ̀n, tí wọ́n á ti máa pà dé láti jọ́sìn, kí wọ́n sì máa kọ́ni lóhun tí wọ́n gbà gbọ́, ìyẹn ti tó.”

Ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ náà dá jẹ́ kó ṣe kedere pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkey ń ṣèdíwọ́ fún ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọn ò fọwọ́ sí i pé “ibi ìjọsìn” ni Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí. Ọ̀gbẹ́ni Ahmet Yorulmaz tó jẹ́ ààrẹ fún àjọ tó ṣojú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílé ẹjọ́, ìyẹn Association in Support of Jehovah’s Witnesses in Turkey sọ pé: “Inú wa dùn gan-an sí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR dá yìí. Ohun tá a wá ń retí báyìí ni pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Turkey fọwọ́ sí i pé ká máa jọ́sìn nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ti ní, kí wọ́n sì pàṣẹ fáwọn aláṣẹ ìlú pé kí wọ́n má fi òfin ilé kíkọ́ dè wá mọ́, ká bàa lè ní àwọn ilé ìjọsìn tuntun lọ́jọ́ iwájú. Tí ìjọba orílẹ̀-èdè Turkey bá lè ṣe ohun tí ilé ẹjọ́ ECHR ní kí wọ́n ṣe yìí, a jẹ́ pé wọ́n tún ti ṣe ohun tó máa jẹ́ káwọn aráàlú túbọ̀ lómìnira ẹ̀sìn nìyẹn.”

Ṣé Ìjọba Orílẹ̀-èdè Turkey Máa Fòpin sí Ẹ̀tanú Ẹ̀sìn?

Látọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni ìṣòro táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ní lábẹ́ òfin lórílẹ̀-èdè Turkey ti ń lójú díẹ̀díẹ̀. Ó ti lé ní àádọ́rin (70) ọdún táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Turkey ti ń kọ̀ láti forúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Àmọ́ lọ́dún 2007, wọ́n gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. *

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkey ti gbé ìgbésẹ̀ láti rí i pé àwọn aráàlú lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Wọ́n ń retí pé kí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR ṣẹ̀ṣẹ̀ dá yìí mú kí ìjọba orílẹ̀-èdè Turkey gba àwọn èèyàn láyè láti máa ṣe ẹ̀sìn wọn, torí Òfin Orílẹ̀-èdè Turkey àti òfin ìjọba àpapọ̀ náà fọwọ́ sí i pé káwọn èèyàn lómìnira ẹ̀sìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wọ̀nà fún ìgbà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Turkey máa ṣe ohun tí ilé ẹjọ́ ECHR sọ, tí wọ́n á fọwọ́ sí i pé “ibi ìjọsìn” ni àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba márùndínlọ́gbọ̀n (25) tí wọ́n ti ní, tí wọ́n á sì jẹ́ kí wọ́n ní àwọn ilé ìjọsìn míì tó bá yá.

^ ìpínrọ̀ 3 Ọ̀rọ̀ nípa “òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti òmìnira ẹ̀sìn” ni Àpilẹ̀kọ 9 dá lé.

^ ìpínrọ̀ 19 July 31, 2007 ni wọ́n dá àjọ Association in Support of Jehovah’s Witnesses in Turkey sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Turkey.