Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

MARCH 7, 2017
SOUTH KOREA

Ìjọba South Korea Ń Fìyà tí Kò Tọ́ Jẹ Dong-hyuk Shin

Ìjọba South Korea Ń Fìyà tí Kò Tọ́ Jẹ Dong-hyuk Shin

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ni ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ń fi sẹ́wọ̀n. Wọ́n tún máa ń fìyà jẹ àwọn tórúkọ wọn ti wà lára ọmọ ogun tí wọ́n lè pè nígbàkigbà pé kí wọ́n wá ṣèrànwọ́ lójú ogun, àmọ́ tí wọ́n wá sọ pé ẹ̀rí ọkàn ò lè jẹ́ káwọn ṣe é mọ́.

Orílẹ̀-èdè South Korea ni Dong-hyuk Shin ń gbé. Nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé, ó mọ̀ pé lọ́jọ́ kan, ìjọba máa pe òun wọṣẹ́ ológun. Gbogbo ìgbà táwọn ológun bá ti ránṣẹ́ sí i ló máa ń lọ. Lọ́dún 2005, ó sin ìjọba tán lẹ́nu iṣẹ́ ológun, wọ́n sì yẹ́ ẹ sí nígbà tó ń lọ. Ni wọ́n bá tún forúkọ ẹ̀ kún àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lè pè nígbàkigbà pé kí wọ́n wá ṣèrànwọ́ lójú ogun, léraléra ni wọ́n sì lè ránṣẹ́ sí i pé kó wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun. Ọdún mẹ́jọ ni wọ́n fi máa ń ṣe é.

Lẹ́yìn tí Ọ̀gbẹ́ni Shin sin ìjọba tán lẹ́nu iṣẹ́ ológun, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀rọ̀ àlàáfíà tí Bíbélì sọ wọ̀ ọ́ lọ́kàn, débi tó fi sọ pé òun ò ní lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ológun mọ́. Nígbà tí ìjọba wá ní kó wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun sí i ní March 2006, ó sọ fáwọn aláṣẹ pé òun ò ní lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ torí ó ta ko ẹ̀rí ọkàn òun.

Wọn Ò Ka Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn Sí

Ìjọba South Korea ò gbà pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kó ṣe é. Lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ogójì [40] ni wọ́n ń ránṣẹ́ sí pé kí gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun tí wọ́n lè pè nígbàkigbà pé kó wá ṣèrànwọ́ lójú ogun, bẹ́ẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí yìí ti sọ pé ẹ̀rí ọkàn ò lè jẹ́ káwọn ṣiṣẹ́ ológun.

Àwọn ológun ò tiẹ̀ ṣe bíi pé àwọn gbọ́ ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Shin sọ nígbà tó ní òun ò lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun tí wọ́n pè é fún. Wọn ò yéé ránṣẹ́ sí i, ìgbà ọgbọ̀n [30] ni wọ́n ránṣẹ́ sí i lọ́dún 2006. Wọ́n ṣì ń ránṣẹ́ sí Ọ̀gbẹ́ni Shin léraléra fún ọdún méje tó tẹ̀ lé e. Àròpọ̀ iye ìgbà tí wọ́n ránṣẹ́ sí i láti March 2006 sí December 2013 pé kó wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun jẹ́ ìgbà méjìdínlọ́gọ́fà [118]. * Torí pé Ọ̀gbẹ́ni Shin máa ń sọ fún tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé òun ò ní lè ṣe é ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá pè é, ìgbà mọ́kàndínláàádọ́ta [49] ni wọ́n fẹ̀sùn kàn án, ìgbà mọ́kàndínláàádọ́rin [69] ló ti fojú ba ilé ẹjọ́ lóríṣiríṣi, ìgbà márùndínlógójì [35] sì ni wọ́n ti dá ẹjọ́ rẹ̀.

“Kò Sọ́gbọ́n Tó Fẹ́ Dá Sí I”

Àwọn ilé ẹjọ́ mọ̀ dáadáa pé ọ̀rọ̀ yìí lágbára lọ́kàn Ọ̀gbẹ́ni Shin, kò fẹ́ ṣohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ rárá. Nínú ọ̀kan lára àwọn ẹjọ́ tí wọ́n dá ní October 7, 2014, Ilé Ẹjọ́ Ulsan sọ pé: “A gbà pé níwọ̀n ìgbà tí [Dong-hyuk Shin] ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sọ́gbọ́n tó fẹ́ dá sí i ju pé kó ṣẹ ìjọba lórí ọ̀rọ̀ yìí, torí ó rí i pé ọ̀kan lòun máa mú, nínú kóun ṣiṣẹ́ ológun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn òun àbí kóun ṣe ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn òun àti ohun tóun gbà gbọ́ mu.”

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ náà gba ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Shin rò, òfin iṣẹ́ ológun tí ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ṣe ti ká àwọn ilé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́ kò. Àpapọ̀ owó ìtanràn tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá [13,000] owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni ilé ẹjọ́ ti ní kí Ọ̀gbẹ́ni Shin san, ẹ̀ẹ̀mẹfà sì ni wọ́n ti rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n, ó kéré tán, oṣù mẹ́fà, àmọ́ wọ́n pa dà ní kó má lọ sẹ́wọ̀n, wọ́n wá fìyẹn dín òmìnira ẹ̀ kù. Nígbà kan, ilé ẹjọ́ ní kó fi ohun tó lé ní ọjọ́ mẹ́jọ ṣiṣẹ́ àṣesìnlú.

Ọ̀gbẹ́ni Shin sọ pé: “Ìbànújẹ́ dorí mi kodò, ọkàn mi ò sì balẹ̀ rárá. Ó ń ṣe mí bíi pé mi ò lè bọ́ ńbẹ̀ láé. Bí mo ṣe ń pààrà ilé ẹjọ́ tún kó ìbànújẹ́ bá ìdílé mi. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́sàn-án tí wọn ò jẹ́ kí n gbádùn yìí, ìyá mi náà ò gbádùn, ọkàn wọn ò balẹ̀, ó sì kó bá ìlera wọn. Ìbànújẹ́ ńlá ló jẹ́ fún mi bí wọn ò ṣe gbádùn torí ọ̀rọ̀ mi. Kò tún wá sówó lọ́wọ́ mi. Torí pé léraléra làwọn aláṣẹ ń pè mí, tí wọ́n ń fẹ̀sùn kàn mí, tí ilé ẹjọ́ sì ń dá mi lẹ́bi, ẹ̀ẹ̀méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo fi iṣẹ́ tí mò ń ṣe sílẹ̀ torí pé mo gbọ́dọ̀ máa fojú ba ilé ẹjọ́, ìyẹn ò sì jẹ́ kí n ráyè dúró níbi iṣẹ́.”

Ìjọba Kọ̀ Láti Tẹ̀ Lé Àdéhùn tí Wọ́n Bá Ìjọba Àpapọ̀ Ṣe

Gbogbo ìgbà tí ilé ẹjọ́ dá Ọ̀gbẹ́ni Shin lẹ́bi ló pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sáwọn ilé ẹjọ́ ní South Korea, àmọ́ ibi pẹlẹbẹ lọ̀bẹ ń fi lélẹ̀. Ẹ̀ẹ̀mẹrin ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ pàápàá fagi lé ẹjọ́ tó pè. Níwọ̀n ìgbà tí Ọ̀gbẹ́ni Shin ò rí nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà ní South Korea, ó kọ̀wé sí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ní June 2016. Ó sọ pé, pẹ̀lú bí ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ò ṣe yéé pe òun wá wọṣẹ́ ológun, tí wọ́n ń pe òun lẹ́jọ́, tí ilé ẹjọ́ sì ń dá òun lẹ́bi, ṣe ni wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí wọ́n fọwọ́ sí nínú ìwé àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights. Ohun mẹ́ta jẹ yọ nínú ọ̀rọ̀ tí Ọ̀gbẹ́ni yìí sọ:

  • Òfin ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé sọ pé, tí ìjọba bá ń pe àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun léraléra pé kí wọ́n wá wọṣẹ́ ológun, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n léraléra, ṣe ni wọ́n ń fi ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní dù wọ́n, torí kì í ṣe bó ṣe yẹ kí nǹkan rí nìyẹn lábẹ́ òfin.

  • Bí àwọn aláṣẹ ṣe ń pè wọ́n léraléra pé kí wọ́n wá wọṣẹ́ ológun yìí, tí wọ́n sì ń fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n, ó fi hàn pé ìjọba fẹ́ fipá mú wọn wọṣẹ́ ológun. Wọn ò jẹ́ kí Ọ̀gbẹ́ni Shin rímú mí, bí wọ́n sì ṣe ń fojú kéré ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ yìí, tí wọ́n ń pè é ní ọ̀daràn torí ohun tó gbà gbọ́ kò bójú mu rárá, wọn ò fọ̀wọ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́.

  • Torí pé ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Shin gbà gbọ́ ni ò jẹ́ kó wọṣẹ́ ológun, ó sọ pé wọ́n fi òmìnira ẹ̀rí ọkàn àti òmìnira ẹ̀sìn du òun.

Ó Ń Retí Ìgbà tí Ìtura Máa Dé

Ọ̀gbẹ́ni Shin ń retí pé Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn yìí máa gbèjà òun, torí léraléra ni Ìgbìmọ̀ yìí ti sọ fún ìjọba South Korea pé kí wọ́n fi àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sílẹ̀, torí ẹ̀tọ́ wọn ni. * Ọ̀gbẹ́ni Shin ń retí pé kí wọ́n ṣèpinnu tó máa gbe àwọn tó wà lára àwọn ọmọ ogun tí ìjọba lè pè nígbàkigbà pé kí wọ́n wá ṣèrànwọ́ lójú ogun. Ó sọ pé: “Mi ò kábàámọ̀ bí mo ṣe dúró lórí ohun tí mo gbà gbọ́, tí mi ò sì fẹ́ ṣohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn mi, àmọ́ mi ò fara mọ́ bí àwọn aláṣẹ ṣe ṣe mí. Mò ń retí ọjọ́ tí ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea máa fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé òun ò ṣiṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò bá jẹ́ kó ṣe é.” Bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tó wà ní South Korea àti káàkiri ayé nìyẹn.

^ ìpínrọ̀ 7 Ìgbà ọgbọ̀n ni wọ́n ránṣẹ́ sí Dong-hyuk Shin lọ́dún 2006, ìgbà márùndínlógójì lọ́dún 2007, ìgbà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún 15 lọ́dún 2008, ìgbà mẹ́sàn-án lọ́dún 2009, ìgbà mẹ́tàdínlógún 17 lọ́dún 2010 àti ìgbà méjìlá 12 lọ́dún 2011. Àmọ́ lọ́dún 2012 àti 2013, wọn ò ránṣẹ́ sí àwọn tí ìjọba lè pè nígbàkigbà pé kí wọ́n wá ṣèrànwọ́ lójú ogun mọ́, torí náà, wọn ò pe Ọ̀gbẹ́ni Shin ní 2012 àti 2013.

^ ìpínrọ̀ 18 Ìpinnu márùn-ún ni Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ti ṣe, torí wọ́n rí i pé ìjọba South Korea ti rú òfin tó wà ní Àpilẹ̀kọ 18, tó sọ̀rọ̀ nípa “òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn”: Yeo-bum Yoon and Myung-jin Choi v. Republic of Korea, Communication No. 1321-1322/2004, U.N. Doc. CCPR/C/88/D/1321-1322/2004 (November 3, 2006); Eu-min Jung et al. v. Republic of Korea, Communication No. 1593-1603/2007, U.N. Doc. CCPR/C/98/D/1593-1603/2007 (March 23, 2010); Min-kyu Jeong et al. v. Republic of Korea, Communication No. 1642-1741/2007, U.N. Doc. CCPR/C/101/D/1642-1741/2007 (March 24, 2011); Jong-nam Kim et al. v. Republic of Korea, Communication No. 1786/2008, U.N. Doc. CCPR/C/106/D/1786/2008 (October 25, 2012); àti Young-kwan Kim et al. v. Republic of Korea, Communication No.  2179/2012, U.N. Doc. CCPR/C/112/D/2179/2012 (October 15, 2014).