Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

JULY 13, 2016
SOUTH KOREA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Míì Tó Wà Lẹ́wọ̀n Lórílẹ̀-èdè South Korea Fẹjọ́ Sùn

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Míì Tó Wà Lẹ́wọ̀n Lórílẹ̀-èdè South Korea Fẹjọ́ Sùn

Láti January, ọdún 2016 ni àwọn ọkùnrin tó lé ní àádọ́ta [50] tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ South Korea tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ti ń kọ̀wé sí àjọ tó ń rí sí títini mọ́lé láìnídìí lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, ìyẹn UN Working Group on Arbitrary Detention (tàbí àjọ Working Group). Àwọn ọkùnrin náà fẹ̀sùn kan ìjọba ilẹ̀ South Korea pé ṣe ni wọ́n ti àwọn mọ́lé láìnídìí torí pé wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n láìka òmìnira ẹ̀sìn àti òmìnira ẹ̀rí ọkàn tí wọ́n ní sí.

Ohun Tó Mú Kí Wọ́n Fẹjọ́ Sùn

Àjọ méjì tó ń bá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣiṣẹ́, ìyẹn àjọ Working Group àti Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, ti pinnu pé ìjọba ilẹ̀ tó bá fi àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sẹ́wọ̀n jẹ̀bi ẹ̀sùn “títini mọ́lé láìnídìí.” * Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ náà ṣe lọ́dún 2014 lórí ọ̀rọ̀ yìí ti jẹ́ kó hàn pé ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea gbọ́dọ̀ dáwọ́ ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun dúró, torí wọn ò mọwọ́-mẹsẹ̀, kí wọ́n sanwó ìtanràn fáwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n, kí wọ́n sì fagi lé ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ yẹn ṣe ló mú kí àpapọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti méjìlélọ́gọ́rin [682] lọ fẹjọ́ sun àjọ Working Group. *

Ìjọba Àpapọ̀ àti Orílẹ̀-èdè South Korea Fúnra Wọn Ń Gbé Ọ̀rọ̀ Náà Yẹ̀ Wò

Tí àjọ náà bá ti fi gbogbo ẹjọ́ táwọn èèyàn náà fi sùn tó ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea létí, tí àjọ náà sì gbọ́ tẹnu ìjọba, àjọ náà máa ṣèdájọ́. Tí wọ́n bá gbà pẹ̀lú àwọn tó fẹjọ́ sùn náà pé ìjọba South Korea jẹ̀bi ẹ̀sùn títini mọ́lé láìnídìí, àjọ náà máa ní kí ìjọba gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ kí wọ́n lè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà, kí ọrùn àwọn ọkùnrin yìí sì mọ́ nínú ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Yàtọ̀ síyẹn, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti Ilẹ̀ South Korea ṣì ń yiiri ohun tí Òfin Iṣẹ́ Ológun sọ wò lọ́wọ́lọ́wọ́, wọ́n sì máa tó ṣèpinnu bóyá wọ́n máa ṣàtúnṣe sí àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ilé Ẹjọ́ yẹn ti mọ̀ pé àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ló ti fẹjọ́ sun àjọ Working Group. Ilé Ẹjọ́ yẹn tún mọ̀ pé Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè UN ti ń rọ ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea léraléra pé kí wọ́n fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é, kí wọ́n sì ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun. Kárí ayé làwọn èèyàn ti fọwọ́ lẹ́rán, tí wọ́n ń retí ohun tí ilé ẹjọ́ gíga ilẹ̀ South Korea máa ṣe, bóyá wọ́n máa fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

^ ìpínrọ̀ 4 Human Rights Council, Opinions adopted by the Working Group on Arbitrary Detention, Ìpinnu No. 16/2008 (Turkey), UN Doc. A/HRC/10/21/Add.1, ojú ìwé 145, ìpínrọ̀ 38 (May 9, 2008). Human Rights Committee, Views, Young-kwan Kim et al. v. Republic of Korea, Communication No. 2179/2012, UN Doc. CCPR/C/112/D/2179/2012, ìpínrọ̀ 7.5 (October 15, 2014).

^ ìpínrọ̀ 4 Lọ́dún 2015, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mọ́kànlélọ́gbọ̀n [631] tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun fẹjọ́ sùn, àwọn mọ́kànléláàádọ́ta [51] míì sì ti kún wọn títí di báyìí lọ́dún 2016.